Aderounmu Kazeem
Loni-in Furaidee, ọjọ Ẹti, ni Gomina Babajide Sanwo-Olu, bẹrẹ abẹwo ẹ sawọn agbegbe ti wọn ti ba nnkan jẹ, ti ọpọ ẹmi tun ṣofo pẹlu.
Ijọba idagbasoke Ajerọmi Ifẹlodun ni gomina yii kọkọ lọ nibi ti wọn ti dana sun mọto, atawọn nnkan mi-in loriṣiiriṣi
Ṣaaju eto abẹwo ọhun lo ti kọkọ kọ ọrọ ibanikẹdun sori ẹrọ ayelujara
abẹyẹfo ẹ, nibi to ti pẹtu si araalu ninu, to si bẹ wọn wi pe ki wọn jẹ ki
ogun o sinmi.
Bakan naa ni Sanwo-Olu, tun ranṣẹ ibanikẹdun sawọn eeyan ti wọn padanu awọn eeyan wọn kaakiri ipinlẹ Eko.
O ni ohun ibanujẹ ni iru akoko yii jẹ pẹlu bi awọn ẹbi kan ṣe padanu awọn eeyan wọn ninu rogbodiyan to n ṣẹlẹ lati bi ọsẹ meji sẹyin.
Bi gomina yii ṣe ke si awọn mọlẹbi ti wọn padanu awọn eeyan wọn, bẹẹ gẹgẹ lo ranti awọn ọlọpaa tawọn naa ku ninu iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si tun padanu teṣan wọn pẹlu.
O ni, “Ko sẹni ti ko ṣe pataki si ijọba Eko, ki Ọlọrun ba wa rọ gbogbo awọn eeyan ti wọn padanu awọn ẹni wọn loju.”