Faith Adebọla. Eko
Idunnu ti ṣubu lu ayọ fawọn oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Eko, latari bi Gomina ipinlẹ naa, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ṣe kede afikun owo-oṣu fun wọn.
Ikede yii waye lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an yii, nigba ti Sanwo-Olu ṣabẹwo si olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Muri-Oluọla, lọọfiisi rẹ to wa ni sẹkiteria ijọba ipinlẹ Eko, to wa lagbegbe Alausa, niluu Ikẹja.
Sanwo-Olu ni gbogbo bi atijẹ-atimu ṣe dogun lorileede yii, latari ọwọn-gogo ọja to gbode kan lawọn ri, ijọba oun si mọ ipọnju ati ipenija to n ba ọpọ awọn oṣiṣẹ ọba finra.
O nijọba ipinlẹ Eko ko ni i ṣẹṣẹ duro de ijọba apapọ lati ṣe eto to tọ fawọn oṣiṣẹ ọba rẹ, tori awọn oṣiṣẹ wọnyi ni ẹnjinni iṣakoso ati iṣẹ ọba nipinlẹ Eko, awọn si mọyi wọn daadaa.
Sanwo-Olu ni: “Mo ti wo kaakiri orileede yii, mo ri i pe nnkan o dẹrun rara. Mo mọ pe ọwọngogo ọja wa niluu, ọrọ naa ki i si ṣe kekere rara.
“Lasiko ipade igbimọ iṣakoso wa, mo ti paṣẹ fun olori awọn oṣiṣẹ ọba ati ẹka to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, idalẹkọọ ati owo-ifẹyinti wọn pe ki wọn bẹrẹ eto lati ṣafikun owo-oṣu gbogbo oṣiṣẹ latoke delẹ lẹnu iṣẹ ọba nipinlẹ Eko.
“Ṣebi ẹyin naa mọ pe dukia ti mo ni to tobi ju lọ ni ẹyin eeyan to n ba ijọba wa ṣiṣẹ. Ko si iye to pọ ju lati san fun oṣiṣẹ, tori pe awọn naa ni wọn n kuku pawo ta a n na ọhun”, gẹgẹ bo ṣe sọ.
Bi Sanwo-Olu ṣe kede ọrọ yii, niṣe lariwo ayọ ati atẹwọ nla pade ikede naa, pẹlu bawọn oṣiṣẹ ṣe ho yee, ti ọpọ wọn si n fo fẹrẹ fayọ, koda awọn mi-in kijo mọlẹ lai ri onilu loju-ẹsẹ.
Orin “Sanwo-Olu, maa ba’ṣẹ rẹ lọ, iṣẹ rẹ ma n tẹ wa lọrun” ni wọn kọ fun gomina wọn ọhun, lati fi ẹmi imoore ati idunnu wọn han.