Faith Adebọla
O deewọ bayii fawọn to n fi ọkada gbe ero, tabi fi i ṣe iṣẹ ounjẹ oojọ wọn, lati gun alupupu naa lawọn ijọba ibilẹ kan nipinlẹ Eko, wọn ni ẹwọn ni wọn fi n ṣere ti wọn ba dan an wo lati ru aṣẹ tuntun naa.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lo kede aṣẹ tuntun naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un yii, lasiko to n ṣepade pataki lori eto aabo, pẹlu awọn lọgaa-lọgaa lẹka eto aabo nipinlẹ Eko. Ile ijọba Eko, ni Alausa, Ikẹja, nipade naa ti waye.
Sanwo-Olu ni bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, wọn ko gbọdọ gburoo ohun to n jẹ ọkada ni tibu-tooro awọn ijọba ibilẹ mẹfa wọnyi: Ikẹja, Surulere, Eti-Ọsa, Lagos Mainland, Lagos Island ati Apapa.
Bakan naa ni Gomina tun ran awọn araalu leti pe ofin to de gigun ọkada lawọn titi marosẹ jake-jado ipinlẹ Eko ṣi wa lẹnu iṣẹ.
O ni o ti waa pọn dandan bayii lati tubọ fẹsẹ ofin yii mulẹ lati mu adinku ba iwa ipanle tawọn ọlọkada kan n hu l’Ekoo.
Lara awọn to wa nipade naa ni gbogbo awọn DPO ati awọn eria kọmanda ileeṣẹ ọlọpaa Eko.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii lawọn ọlọkada kan ti wọn fura si pe Mọla ni wọn, ṣe akọlu si Ọgbẹni Sunday David Umoh, lagbegbe Lẹkki, ọrọ nipa ṣenji muri marun-un lo faja, ni wọn ba bẹrẹ si i lu u ni kumọ, wọn si lu u pa, wọn tun dana sun un.
Awọn eleṣu ẹda naa tun ṣe meji ninu awọn alájọṣiṣẹ́pọ oloogbe naa, Francis Olatunji ati Philip Balogun, leṣe.