Faith Adebọla, Eko
Awọn iyawo awọn ọlọpaa mẹfa to doloogbe lasiko rogbodiyan SARS ti dupẹ gidigidi lọwọ Gomina Sanwo-Olu latari bo ṣe fun wọn lẹbun owo, miliọnu mẹwaa naira fẹnikọọkan wọn ati ẹkọ-ọfẹ to tun fun aọn ọmọ wọn.
Ọsan Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni eto naa waye ni gbọngan Civic Centre, Victoria Island, nibi ijiroro lori eto aabo ẹlẹẹkẹrinla ti wọn ṣe.
Nigba to n fun awọn obinrin naa niwee sọwedowo wọn, Sanwo-Olu ni oun ba wọn kẹdun fun bi wọn ṣe di opo airotẹlẹ, latari pe awọn ọkọ wọn fẹmi wọn lelẹ, wọn sapa lori ọrọ aabo gbogbo wa titi doju iku, lasiko rogbodiyan SARS to waye laipẹ.
Orukọ awọn ọlọpaa mẹfẹẹfa to jade laye lasiko laasigbo naa ni Inpẹkitọ Ayọdeji Erinfọlami, Inpẹkitọ Aderibigbe Adegbenro, Inpẹkitọ Samsom Ehibor, Inspector Igoche Cornelius, Sajẹnti Bejide Abiodun ati ASP Yaro Edward.
Yatọ si owo, Sanwo-Olu tun kede pe gbogbo awọn ọmọ oloogbe ni ijọba ipinlẹ Eko maa ran lẹkọọ-ọfẹ lati ipele yoowu ki wọn wa titi wọ yunifasiti.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, toun naa wa nikalẹ sọ pe nnkan iwuri nla ni ohun ti gomina ṣe jẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa, eyi yoo si tubọ mu kawọn tẹra mọṣẹ gidi, pẹlu igbọkanle pe ijọba mọyi awọn, wọn si mọ riri ẹmi awọn.
Bakan naa ni ọkọọkan awọn iyawo ọlọpaa mẹfa to gba ẹbun gba-ma-binu naa dupẹ lọwọ gomina ati ijọba rẹ, wọn ni bo tilẹ jẹ pe owo ko to ẹmi, sibẹ, o jọ awọn loju pe ijọba ko jẹ ki iku ololufẹ awọn ja si asan, wọn si ṣadura fun gomina Eko.