Faith Adebola, Eko
Owo ti iye rẹ to tiriliọnu kan, biliọnu ẹẹdẹgbẹrin din mẹjọ, miliọnu ọrinlelẹgbẹta ati mẹwaa, ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgberin din meje, ẹẹdẹgbẹrun le mẹrin Naira (₦1,692,670,753,894) ni ijọba ipinlẹ Eko yoo na sori igbokegbodo iṣẹ ọba ati ipese awọn ohun amayedẹrun lọdun 2023 ta a fẹẹ mu yii.
Ṣe ẹnu onikan la a ti i gbọ pọn-un, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, naa lo sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, lasiko to n gbe aba eto iṣuna 2023 kalẹ niwaju awọn aṣofin ipinlẹ Eko. Gbọngan apero awọn aṣofin naa, eyi to wa l’Alausa, leto yii ti waye.
Ẹkunrẹrẹ alaye n bọ laipẹ.