Sanwo-Olu wo awon ile kan ni Banana Island, o ni wọn lufin ijọba


Nitori ti wọn kọle si ibi ti omi le maa gba kọja lawọn eeyan kan ṣe padanu ile wọn lagbegbe Banana Island, lẹgbẹẹ Ikoyi, niluu Eko, lọjọ Aje, Mọnde, nigba ti ijọba Eko wo wọn danu.

Alaye ti ijọba Eko ṣe lori igbesẹ yii ni pe awọn lanlọọdu kan lagbegbe naa ko gbawe aṣẹ ki wọn too kọ awọn ile wọn, ati pe pupọ ninu wọn naa lo kọle ọhun si ibi ti omi yẹ ko maa gba ṣan lọ.

Kọmiṣanna fun idagbasoke ilu ati ilana ile kikọ, Dokita Idris Salakọ, ni bo tilẹ jẹ pe ijọba ti sọ fun awọn eeyan ọhun tẹlẹ pe ki wọn dawọ iṣẹ ti wọn n ṣe duro, sibẹ niṣe ni wọn tẹsiwaju pẹlu ohun ti wọn n ṣe.

“Lọjọ Aiku, Sannde, ni Gomina Babajide Sanwo-Olu yọju sibi, ohun to si sọ ni pe gbogbo ile ti ki i ba ṣe pe ijọba ti fọwọ si kikọ ẹ, loju-ẹsẹ ni ki a wo wọn lulẹ. Fun idi eyi, awa naa ti ṣetan bayii lati maa lọ kaakiri lati ri i pe awọn eeyan n tẹle aṣẹ ijọba nipa ile kikọ.

“Ohun to ṣẹlẹ ni pe gbogbo ile ti wọn ba ti kọ soju agbara to yẹ ki omi maa gba ṣan lọ la oo wo danu. Ofin wa nipinlẹ Eko to fofin de iru iwa bẹẹ, o si pọn dandan ki awọn eeyan tẹle e.”

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe awọn ile ti ijọba wo danu yii ni wọn lu ofin ọhun lori bi wọn ṣe kọ wọn di oju agbara ati ibi ti omi le maa gba ṣan lọ.

Leave a Reply