Jọkẹ Amọri
Ṣẹnkẹn ni inu awọn agba oṣere ilẹ wa bii Idowu Phillips ti gbogbo eeyan mọ si Iya Rainbow, Adewale Ẹlẹsho, Baba Ẹda Onile-Ọla, Agbako, Madam Ṣajẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ n dun. Eyi ko sẹyin eto ilera ma-da-mi-dofo ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu ṣe fawọn agba oṣere ilẹ wa.
Lasiko to gbalejo wọn nile ijọba lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lo kede ipinnu rẹ lati fi eto yii ran awọn oṣere ti wọn ti dagba lọwọ, ki wọn le lanfaani si ilera ara wọn.
Nigba to n sọrọ lori awọn alejo to gba naa, Sanwoolu ni, ‘Mo gba alejo awọn oṣere tiata ilẹ wa lati fi imọriri mi han si ipa takuntakun ti wọn n ko lawujọ.
‘‘Bakan naa ni mo tun lo anfaani yii lati ṣe idasilẹ ma-da-mi-dofo fun wọn ki wọn le ni anfaani si ilera pipe.’’
Niṣe ni jijẹ mimu n ṣan nibi igbalejo naa, awọn oṣere wọnyi ko le pa idunnu wọn mọra lori ohun ti gomina ṣe fun wọn yii.