Bi ọdun 2023 ti ṣe n sun mọ etile lawọn ẹgbẹ oṣelu ti bẹrẹ oriṣiriiṣii igbesẹ lati yanju aawọ to wa ninu ẹgbẹ, ki wọn baa le rọwọ mu ninu eto idibo ti yoo waye lọdun naa.
Lọjọ Iṣẹgun lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kora wọn jọ lati ṣepade pẹlu Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Goodluck Ebele Jonathan.
Lori ikanni abẹyẹfo aarẹ ile igbimọ-aṣofin agba tẹlẹ, Bukọla Saraki, lo kọ ọrọ ọhun si pe awọn ṣepade pẹlu Jonathan lojuna lati pẹtu si oriṣiiriṣii aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ awọn.
Bẹẹ ni fidio kan wa lori ikanni ọhun, ninu eyi ti wọn ti fi Jonathan han bo ti ṣe n ki wọn kaabọ sipade naa.
Saraki sọ pe, “Lojuna lati tẹti si kaluku, paapaa awọn to jẹ alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ, lori ohun to n dun wọn la ṣe n ṣepade lọsan-an yii pẹlu Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Goodluck Ebele Jonathan.”