Faith Adebọla
Aarẹ ileegbimọ aṣofin agba ana, Oloye Abubakar Bukọla Saraki, ati aarẹ ilẹ wa tẹlẹ ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti wa ninu ipade kan l’Abẹokuta, ṣugbọn niṣe ni wọn tilẹkun mọri ṣepade naa, wọn o jẹ koniroyin kankan yọju sibẹ.
ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni Saraki ati ikọ rẹ lọọ ṣabẹwo si Oloye Ọbasanjọ ni ile ikoweesi rẹ, iyẹn Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library, to wa lọna Oke-Mọsan, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Awọn mi-in to wa pẹlu Saraki, ti wọn jọ wọle sibi ipade naa ni awọn ọmọ igbimọ apẹtusaawọ ẹgbẹ oṣelu PDP, eyi ti Saraki jẹ alaga fun. Lara wọn ni Alaaji Ibrahim Shehu Shema, Ibrahim Hassan Dankwabo, Gomina ipinlẹ Rivers nigba kan, Liyel Imoke, Sẹnetọ Mulikat Akande Adeọla, ati gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹri, Ọlagunsoye Oyinlọla.
Ko ti i sẹni to mọ pato ohun ti ipade naa da le lori, ṣugbọn awọn amoye ti n sọ pe apero wọn ko ṣẹyin ipalẹmọ tawọn oloṣelu n ṣe lati mura de eto idibo gbogbogboo ọdun 2023.