Saraki gba Buhari nimọran lori eto aabo to mẹhẹ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Olori ile-igbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa tẹlẹ, Ọmọwe Bukọla Saraki, ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari nimọran nipa eto aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede yii, o ni ki Aarẹ yee da kinni naa ṣe.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun 2021, ni Bukọla Saraki sọ pe ki Aarẹ Buhari gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako naa mọra lati ran an lọwọ lori bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria, to jẹ ijinigbe ati ipaniyan lo gbode kan.

Ilu Abẹokuta ni Saraki ti sọrọ yii nigba to ṣabẹwo si Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ  nile rẹ to wa ni OOPL.

Nnkan bii aago mejila kọja iṣeju mejila ni Saraki balẹ sile Ọbasanjọ pẹlu awọn isọngbe rẹ, wọn si jọ tilẹkun mọri ṣepade titi.

Nigba ti ọkunrin naa jade sita lawọn oniroyin beere ọrọ ọlọkan-o-jọkan lọwọ rẹ, nibẹ lo si ti mẹnu ba a pe ipade apero gidi lohun to wa nilẹ bayii gba, ki i ṣe pe ki Aarẹ nikan maa da a ṣe.

Saraki sọ pe, ‘‘Imọran mi funjọba ni pe iṣoro ta a ni yii kọja ohun ti ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba nikan yoo koju, mo ro pe asiko ti to lati gba awọn ẹgbẹ alatako naa laaye lati da si i, pẹlu awọn ọrẹ wa lati ilẹ okeere.

‘‘Iṣoro ta a ni pọ, o si yẹ ka yanju wọn. Ba a ṣe n sọrọ ọpọ oloṣelu la n sọrọ nipa 2023, iyẹn ṣi ku ọdun meji. Ojuṣe wa ni pe ka ri i daju pe ki ọdun meji yẹn too pe, a ti kora wa jọ lati ṣapero lori ohun ti kaluku ba mọ. Ka jọ jokoo yi tabili po lati mọ ibi ti a n lọ ni Naijiria’’

Nipa ohun to waa ṣẹ lọdọ Ọbasanjọ gan-an, Saraki sọ pe oun waa sọ ohun tawọn fẹẹ ṣe fun un ni, o si ni ọrọ Naijiria lo jẹ oun logun, gẹgẹ bi Ọbasanjọ ṣe maa n sọ ọ pe oun ko si fun ẹgbẹ oṣelu, bi ko ṣe ilọsiwaju Naijiria nikan.

 

Leave a Reply