Faith Adebọla
Afurasi ọdaran kan, Ifechukwu Tom Makwe, ṣugbọn to jẹ Sẹnetọ Tompolo lawọn obinrin oyinbo mọ ọn si, to si tun maa n pe ara ẹ ni Sẹnetọ Fahad Makwe, tabi Dokita Bran fawọn mi-in, ti wa lakolo awọn ẹṣọ ajọ to n ri si iwa jibiti lilu, ṣiṣe owo ilu mọkumọku atawọn iwa ajẹbanu gbogbo nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), bayii, ibẹ lo ti n gbatẹgun alaafia lori ẹsun pe o lu jibiti ori ẹrọ ayelujara fun obinrin oyinbo kan, obitibiti owo ilẹ okeere ti wọn niye rẹ din diẹ ni miliọnu mẹfa owo yuro (5.7 million euros) lo ko wọn nifaa rẹ, ifa ọhun si ti i fa a lẹnu ya bayii.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Guzape, niluu Abuja, olu-ilu Naijiria, lọwọ awọn EFCC ti tẹ jagunlabi yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, ninu ile fulaati kan lagbegbe ọhun ni ayederu sẹnetọ yii fori pamọ si, to ti n fi ẹrọ kọmputa ati foonu wọ owo jade ninu akaunti awọn ẹni ẹlẹni, to si n purọ oriṣiiriṣii lati ṣe awọn ti wọn fọkan tan an ni ṣuta.
ALAROYE gbọ pe obinrin ara ilẹ Spain kan ti wọn forukọ bo laṣiiri lafurasi ọdaran yii ṣe gbaju-ẹ buruku kan fun, to si fẹtan gba obitibiti owo lọwọ ẹ.
Wọn niwadii ti fidi ẹ mulẹ pe yatọ si bo ṣe n pe ara ẹ ni aṣofin agba ilẹ Naijiria fawọn oyinbo, ẹtan nla kan t’afurasi yii fi mu obinrin ọmọ ilẹ Spain to lu ni jibiti ni pe o sọ fobinrin naa pe ọga agba ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ orileede Amẹrika, iyẹn US Federal Bereau of Investigation, FBI, loun, o loun tun n ṣiṣẹ bii ejẹnti wọn, oun si jẹ ọkan lara awọn lọọya to dantọ, ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika n lo, bẹẹ lo pese awọn ẹri awuruju kan bayii, lati mu ẹni to n ba sọrọ nigan-an, niyẹn ba ko si pampẹ jibiti rẹ.
Wọn niwadii tun fidi ẹ mulẹ pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ fun Ifechukwu yii, wọn ni lati ọdun 2013 ni wọn ti n roye iṣẹ laabi rẹ, ti wọn si ti n wa a, amọ ti wọn o ri i mu. Amọ sibẹ, ago lo de adiẹ rẹ gbẹyin.
EFCC ti ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii, ati pe lẹyin iwadii, ko si idaduro kankan mọ, afurasi naa yoo lọọ foju rinju pẹlu adajọ ni, ibẹ si ni wọn yoo ti kawe ofin si i leti daadaa lori aṣa palapala ọwọ ẹ yii.