Sẹnetọ Oriolowo fẹẹ wọ Gomina Adeleke lọ si kootu, o lo  b’oun lorukọ jẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nileegbimọ aṣofin agba, Adelere Oriolowo, ti leri pe oun yoo wọ Gomina Ademọla Adeleke lọ si kootu ti ko ba tọrọ aforiji lori bi wọn ṣe ba a lorukọ jẹ.

Laipẹ yii ni igbimọ kan ti Adeleke gbe kalẹ lati ṣewadii awọn dukia ijọba to wa nita fẹsun kan Oriolowo pe awọn manṣinni nla nla ti wọn maa n lo ninu oko (farm) bii Motor Grader, Bulldozer ati Soil Compactor wa ni sakaani rẹ.

Ṣugbọn nigba to n ba Alaroye sọrọ, Oriolowo ni ohun ti eeyan yoo reti lọdọ igbimọ to fẹẹ ṣe iru iṣẹ bẹẹ ni pe ki wọn pe ẹni ti wọn fẹsun kan lati gbọ tẹnu ẹ, ko si wi awijare ko too di pe wọn yoo ṣedajọ ẹ.

Aṣofin agba yii fi kun ọrọ rẹ pe oun ko ri iwe ipe kankan latọdọ awọn igbimọ yii, bẹẹ ni wọn ko pe ẹrọ ibanisọrọ oun lati gbọ tẹnu oun, eleyii si fihan pe ṣe ni wọn mọ-ọn mọ fẹẹ ba oun lorukọ jẹ.

Oriolowo ni gbogbo maṣinni ti wọn n sọ yii lo wa ni sakaani ijọba lọwọlọwọ, to ba jẹ pe wọn ṣiṣẹ iwadii wọn daadaa ko too di pe wọn sare gba ọdọ awọn oniroyin lọ, o ni oun ko mu nnkan to jẹ tijọba mọ ẹru oun fun odidi ọdun mẹẹẹdogun toun fi ṣiṣẹ nipinlẹ Ọṣun.

O ni irọ ti wọn pa mọ oun yii ti tabuku ba orukọ oun, ti awọn ololufẹ oun si n pe oun lọtun-un-losi pe bawo lo ṣe jẹ, nitori idi eyi loun si ṣe sọ fun agbẹjọro oun lati kọ iwe sijọba ipinlẹ Ọṣun.

Ninu iwe naa, eleyii ti wọn ti gbe siwaju gomina ni Oriolowo ti beere pe kijọba tọrọ aforiji lọwọ oun, ki wọn si san owo gba-ma-binu miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira fun oun, ai jẹ bẹẹ, awọn yoo pade ni kootu.

Leave a Reply