Dada Ajikanje
Seriki Fulani niluu Igangan, nijọba ibilẹ Ibarapa, Alhaji Salihu Abdulkadir, ti sọ pe meje ninu awọn mọlẹbi oun ni Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin ẹ pa, ti wọn tun ba dukia tiye ẹ jẹ ẹẹdẹgbẹta (N500m) miliọnu naira jẹ.
Niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni olori awọn Fulani darandaran tawọn Sunday Igboho sọ pe awọn ko fẹẹ ri mọ lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, ti sọrọ yii.
O ni, iya nla ni awọn Yoruba fi jẹ oun ati mọlebi oun lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan ti wọn fi kan oun atawọn eeyan oun yii.
Seriki Fulani fi kun ọrọ ẹ pe ile oun ati oriṣiiriṣii mọto bii mejila, ti toun ati tawọn ọmọ pẹlu ti awọn alejo ti wọn wa oun wa pata ni wọn dana sun, ti meje ninu mọlẹbi oun paapaa tun ba iṣẹlẹ naa lọ.
O ni titi di asiko yii lawọn ko ti i ri meji ninu oku awọn eeyan ti wọn kọ lu ọhun, bẹẹ ni awọn to kogun ja awọn yii tun ko awọn ni maaluu lọ.
Alhaji Salihu Abdulkadir, yii tun sọ pe ti wọn ba n sọ nipa ijinigbe, ko si ẹni to mori bọ lagbegbe naa, nitori bi awọn Fulani kan ṣe n ji eeyan gbe, bẹẹ lawọn ọmọ Yoruba mi-in naa n ṣe bẹẹ.
Siwaju si i, o ni gbogbo awọn oloye atawọn ọjọgbọn ti wọn wa ni agbegbe ti oun n gbe yii naa ni wọn mọ pe oun maa n fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro atawọn alaṣẹ lati jọ gbogun ti iwa to ba le di alaafia ilu lọwọ.
“Nigba ti wọn fẹsun ifipa-banilopọ kan ọm̀ọ Fulani kan, Ọmọmọgeto, emi yii gan-an ni mo ṣewadii bọrọ ọhun ṣe jẹ, ti mo si fa ọmọ to huwa ọdaran yii le awọn obi ọmọ to hu u si lọwọ lati le fi gbe igbesẹ to yẹ. Bẹẹ gẹgẹ lo tun sọ pe ko si oko ti wọn sọ pe awọn Fulani fi maaluu bajẹ ti oun ko ni i gbe oniṣẹ dide lati lọọ wo o pẹlu iwadii, ati pe ti ọrọ ọhun ba si ti ri bẹẹ, niṣe ni oun yoo pa Fulani bẹẹ laṣẹ ko sanwo fun ẹni ti wọn ba nnkan ẹ jẹ.
Ọmọ Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni Seriki Fulani yii pe ara ẹ, bẹẹ lo sọ pe ko si ootọ kankan ninu ẹsun ti Sunday Igboho atawọn eeyan ẹ fi kan oun pe oun ni agbodegba fawọn ti wọn n ji eeyan gbe niluu Ibarapa ati agbegbe ẹ.
O ni, ọgbọn lati le awọn Fulani kuro lagbegbe ọhun ati ilẹ Yoruba lapapọ ni wọn n da ti wọn fi pa iru irọ bẹẹ mọ oun.
Ninu ọrọ ẹ naa lo tun ti sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku Dokita Aborode ti wọn sọ pe awọn Fulani lo pa a. Bakan naa lo sọ pe nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye fẹẹ to irin wakati meji si abule ti oun ti gbe pẹlu ọmọ ati iyawo fun aadọta ọdun.
Seriki Fulani yii ti waa ke si ijọba apapọ lati ṣewadii iṣẹlẹ yii, bẹẹ lo sọ pe ko daju pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo le ṣe ohunkohun, ti wọn ba da ọrọ ọhun nikan da Gomina Ṣeyi Makinde.