Faith Adebọla
Oju ina kọ lewura n hu irun lọrọ da fun Seriki Fulani ilu Igangan, Alaaji Saliu Abdulkadir, pẹlu bi baba naa ṣe ni atigbo de igbo loun atawọn eeyan fi ọrọ ara awọn ṣe, lasiko ti wọn sa kuro niluu naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ki wọn too rin yọ si agbegbe ipinlẹ Ogun laaarọ ọjọ Satide yii.
Ninu ọrọ to ba akọroyin Saharareporters sọ lori foonu, o ni: “Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, inu igbo la wa, ẹsẹ la fi n rin sa kuro niluu, wọn ti dana sun mọto wa bii mọkanla. Awọn ọmọ mi fara pa, wọn si yinbọn lu awọn eeyan wa kan, ṣugbọn ko ti i sẹni to ku o. Ọna ati gbe awọn to fara gbọgbẹ lọ ọsibitu ni mọ n ṣan bayii.”
“Awọn bọisi yẹn yinbọn lu awọn ọmọ mi atiyawo mi, Allah lo yọ wọn. Wọn tun yinbọn lu alabaagbele wa kan, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko sẹni to ku. Ori irin la wa ni gbogbo oru ọjọ Ẹti titi ta a fi de ibi ta a wa yii, ṣugbọn aabo diẹ ṣi wa fun wa nibi yii.
”Mo ti wa pẹlu awọn eeyan mi nipinlẹ Ogun nibi, ṣugbọn mi o ti i ri awọn ọmọ mi kan. Bi mo ṣe fẹẹ gbe awọn to fara pa lọ ọsibitu ni mọ n wa bayii, ki wọn le ri itọju gba.”
Lati ọjọ Ẹti ni wahala ti de ba baba naa atawọn Fulani agbegbe ọhun latari bi ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Igboho Ooṣa ṣe wọlu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, o loun waa ran olori awọn Fulani naa atawọn eeyan ẹ leti gbedeke toun fun wọn pe wọn ko gbọdọ kọja ọjọ meje ki wọn too kangara wọn kuro lagbegbe ọhun. O lọrọ naa ki i ṣe ṣereṣere rara o, tori iru oun ko le wa niluu kawọn alejo maa dun mọhuru-mọhuru mọ ọmọ oniluu, debi ti wọn fi n ji wọn gbe, ti wọn n pa wọn bii ẹran. O niyẹn gbọdọ dopin bayii, ko si sohun meji ju kawọn Fulani naa fi ilu ati agbegbe Oke-Ogun silẹ lọ.
Bi Sunday Igboho ṣe n pari ọrọ rẹ lawọn ọdọ fariga, wọn tina bọ ile Seriki Fulani yii, ti wọn sun awọn ọkọ ayọkẹlẹ to wa nibẹ pẹlu, lọrọ ba di bo-o-lọ-o-yago fawọn Fulani agbegbe naa, ti kaluku wọn n sa kijokijo, ti wọn sa asala fun ẹmi wọn.
Abdulkadir sọ pe wahala naa lo le oun, awọn iyawo oun atawọn ọmọ jade, awọn o si le duro mu ohunkohun ju aṣọ to wa lọrun awọn yii lọ. O ni gbogbo dukia awọn, ati mọto mọkanla ni wọn dana sun, o niṣoju awọn ọlọpaa, awọn ikọ Operation Burst atawọn agbofinro mi-in lawọn ọdọ yii fi n sọna si dukia awọn, sibẹ ti wọn o ṣe nnkan kan.
Ninu iṣẹlẹ mi-in to fara pẹ eyi, wọn ni niṣe lawọn ṣọja n lu awọn araalu nilukilu lati daabo bo awọn Fulani to n sa lọ naa atawọn maaluu wọn.
Ṣe, ninu ọrọ ti Sunday Igboho sọ niluu Igangan lọjọ Ẹti, o paṣamọ ohun to ṣẹlẹ, o ni lati ọjọ toun ti fun awọn Fulani ni gbedeke ọsẹ kan nijọba ti ko awọn ṣọja wa sagbegbe yii lati waa daabo bo awọn Fulani, bẹẹ latigba ti wọn ti n pa awọn agbẹ Yoruba, ti wọn n ji wọn gbe, ijọba o ko ṣọja wa o.
Ọrọ yii jọra pẹlu bawọn eeyan ijọba ibilẹ Ariwa Yewa, nipinlẹ Ogun, to jẹ amulẹgbẹẹ agbegbe Ibarapa si Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ṣe kegbajare pe niṣe lawọn Fulani ati ṣọja to n ṣọ wọn mu kawọn da bii ekute ti ologbo n dọdẹ rẹ bayii lori ilẹ awọn.
A gbọ pe lawọn igberiko ati abule tawọn Fulani naa ba de pẹlu maaluu wọn, tawọn ara abule ba kọ lati faaye gba wọn pe kẹran wọn jẹko nibẹ, alupamokuu lawọn ṣọja naa maa fi tiwọn ṣe.
Apẹẹrẹ kan lohun ta a gbọ po ṣẹlẹ labule Ubeku, ni ijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ninu oṣu kejila, ọdun to lọ yii, nigba tawọn Fulani ti kọkọ da maaluu rẹpẹtẹ wa sagbegbe naa lati jẹko, ṣugbọn tawọn araalu kọ jalẹ fun wọn, lawọn Fulani naa ba lọ.
Ṣugbọn lọjọ kọkandilogun, oṣu naa, ni wọn lawọn ṣọja bii mẹwaa dihamọra ogun wa lati bareke wọn to wa l’Alamala, ni Abẹokuta, nipinlẹ Ogun. Nnkan bii aago meji ọsan ni wọn wa ọkọ ologun wọn de, wọn lọ taara sọdọ baalẹ abule naa, wọn si sọ fun un pe awọn waa ṣekilọ fun un ni o, pe ko sọ fawọn eeyan ẹ pe ko sẹni to gbọdọ di awọn Fulani darandaran lọwọ tabi le awọn maaluu wọn lagbegbe naa, aijẹ bẹẹ, awọn ologun yoo fija pẹẹta pẹlu wọn.
Loṣu Januari yii, labule Agbọn-Ojodu, wọn ni niṣe lawọn Fulani naa n lọ kaakiri abule ati ileto to wa nibẹ, ti wọn n naka si ẹnikẹni ti wọn ba ri, wọn n fẹsun kan wọn pe wọn o jẹ kawọn fi maaluu wọn jẹko.
Ọkunrin kan, Gabriel Mulero, ni ibi toun ti n ṣiṣẹ ọkada oun jẹẹjẹ loun wa ti Fulani kan fi tọka soun, lawọn ṣọja to tẹle e ba gba oun mu, wọn gba oun leti leralera, ni wọn ba da oun dọbalẹ, wọn si bẹrẹ si i fi koboko ọwọ wọn lu oun, bẹẹ ni wọn n fi bata kobita wọn gba oun nipaa.
Bi wọn ṣe wi, ko siyatọ ninu ohun to n waye lawọn abule ati igberiko bii mọkandinlọgbọn to wa lagbegbe yii. Bi awọn iṣẹlẹ ifiyajẹni, fifi maaluu jẹko lọran-anyan, fifi ṣọja halẹ mọ ni yii ṣe n waye l’Agbọn-Ojodu ati Atẹru, bẹẹ naa lo n ṣẹlẹ ni Moro, Ologun, Agbọn, Igbọta, Ogunba-Aiyetoro, Oke-Odo, Ibọrẹ, Gbọkoto, Iselu, Ijalẹ, Ohunbẹ, Igbẹmẹ, Owode-Ketu, Igan-Alade, Lashilo, Ọja-Ọdan, Iyana Mẹta, Igboorọ, Ẹgbẹda ati Kuṣẹ.
Ṣe oniluu kan ko ni i fẹ ko tu, awọn iwa idunkooko ati ifiyajẹni lati gbeja awọn Fulani darandaran wọnyi lo mu kawọn ọba alaye agbegbe naa sọ pe awọn o le kawọ gbera maa woran lasan, kawọn Fulani ati ṣọja waa mu awọn lẹru lori ilẹ ati oko awọn.
Awọn ọba alade mẹta agbegbe ọhun, Oniggua ti ilẹ Uggua, Ọba Micheal Adelẹyẹ Dosumu, Eselu of ilẹ Iselu, Ọba Akintunde Ebenezer Akinyẹmi ati Alademeṣọ ti Igan Alade, Ọba Gabriel Olukunle Ọlalọwọ, ti pawọ-pọ kọ lẹta pajawiri kan lọjọ keje, oṣu ki-in-ni, ọdun yii si Kọmanda awọn ṣọja Artillery Brigade, to wa l’Alamala, Abẹokuta, ati si kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti wọn si fi ẹda ṣọwọ si Gomina Dapọ Abiọdun pẹlu.
Nibi tọrọ de yii, pẹlu ohun to ṣẹlẹ n’Igangan yii, ati bi Sunday Igboho ṣe leri pe ki i ṣe Oke-Ogun nikan loun n ja fun, ṣugbọn gbogbo ilẹ Yoruba pata ni, ko ti i sẹni to mọbi ta a maa ba yara ja lori ọrọ naa. O jọ pe ojo to n rọ lọwọ lọrọ yii, ko ṣeni to le sọ iye eeyan ti yoo pa o.