Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ, Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Serkin Fulani ipinlẹ Kwara, Hardo Usman Adamu, atawọn meji miiran ti wọn fẹsun ijinigbe kan fara han niwaju Onidaajọ Adenikẹ Akinpẹlu, ni ile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo lori ẹsun ijinigbe, sugbọn ni kete ti awọn ẹlẹrii yọju ni kootu nigba ti igbẹjọ n lọ lọwọ ni Adamu subu lulẹ, to si daku.
Agbẹjọro rẹ Barrister Adebayọ Adelọdun SAN, rọ ile-ẹjọ lati gba beeli onibaara rẹ tori ilera rẹ, ko si fun un laaye lati lọọ gba itọju nileewosan Jẹnẹra tiluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ naa.
Adajọ Adenikẹ, gba si agbẹjọro naa lẹnu, o ni ki wọn gbe Adamu lọ sileewosan Jẹnẹra fun itọju o sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọdun 2023.
Leyin igbẹjọ yii ni atẹjade kan ti Akọwe ẹgbẹ Fulani darandaran ni Kwara, Muhammad Madobbo, atawọn mẹwaa miiran buwọ lu jade, leyii ti wọn ti rọ Ẹmia ilu Ilọrin, Dokita Ibrahim Zulu Gambari, lati rọ Serkin Fulani naa, Hardo Usman Adamu, loye Shugaban Fulani, to di mu, titi ti idajọ yoo fi waye nile-ẹjọ lori ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan an, ki wọn si ri i pe idajọ ododo waye lori ẹnikẹni ti aje iwa ijinigbe naa ba ṣi mọ lori, ki Ẹmia si yan Serkin Fulani miiran gẹgẹ bii adele.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni wọn mu olori awọn Fulani Ìlọrin yii, wọn lo mọ nipa awọn ijinigbe oriṣiiriṣii to n ṣẹlẹ ni Kwara, eyi ni wọn fi taari oun atawọn meji kan lọ si ọgba ewon to wa loke Kúrá, n’Ilọrin