Sidika tọju kokeeni sinu bata to n wọ lọ si Mẹka

Monisọla Saka, Eko

Ọwọ ṣinkun ajọ to n gbogun ti iwa gbigbe oogun oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ obinrin opo ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) kan, Kẹhinde Sidika Ajiṣegiri, lasiko ti obinrin ọlọmọ mẹrin naa n gbiyanju lati gbe egboogi oloro ti wọn n pe ni kokeeni to to iwọn irinwo giraamu (400 grammes) lati Eko lọ siluu Mẹka, lorilẹ-ede Saudi Arabia, lọhun-un.

Ni papakọ-ofurufu Murtala Mohammed, to wa n’Ikẹja, niluu Eko, ni  wọn ti mu obinrin yii, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Inu bata rọba dudu to wọ s’ẹsẹ ni wọn fura si pe o gbe oogun oloro naa si, nigba ti ẹrọ to n ṣayẹwo awọn ero to fẹẹ wọ baaluu bẹrẹ si i han gan-an-ranran, eyi to tumọ si pe ẹni naa lẹbọ lẹru. Wọn yẹ gbogbo ara abilekọ yii atẹru rẹ wo, wọn ko ri nnkan kan, ni wọn ba ko bata ẹ sori ẹrọ naa, ibẹ laṣiiri ti tu.

Lẹyin ti wọn da obinrin naa duro, wọn la bata ẹsẹ ẹ mejeeji to wọ si meji, ibẹ ni wọn ti ri lailọọnu meji pelebe to pọn egboogi oloro ọhun si ko too ṣẹṣẹ waa ko o saarin awọn bata naa, o si lẹ ẹ pa mẹrẹnmẹrẹn pada bii pe ọwọ ko kan bata yẹn ri.

Ninu fidio atawọn fọto kan ti Alukoro ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, fi lede lori iṣẹlẹ yii ni wọn ti ṣafihan bi akara iwa ọdaran yii ṣe tu sepo, tọwọ si ba a. Ṣe ẹni to ba mọ nnkan i fi pamọ gbọdọ ranti ẹni ti mọ nnkan i wa dori okodoro.

Afurasi ọdaran to pe ara ẹ ni oniṣowo yii sọ pe aṣọ ati bata agbalagba ati tọmọde loun n ta ninu ọja Idumọta, l’Ekoo, ati pe ọja loun fẹ lọọ ra lorilẹ-ede Saudi toun n lọ, oun si tun fẹẹ de Mẹka, lati ṣe isin mimọ f’Ọlọrun.

Wọn niwadii ṣi n tẹsiwaju, ati pe laipẹ ni wọn yoo foju afurasi naa ati egboogi to lẹ mọ bata ọhun bale-ẹjọ, ko le lọọ fimu kata ofin.

Olori ajọ NDLEA, Mohammed Buba Marwa, ti gbe oṣuba sadankata fawọn ọmọ abẹ ẹ fun iṣẹ takuntakun ati ilakaka wọn lati fopin si iwa gbigbe egboogi oloro nilẹ yii.

Leave a Reply