Ohun ti ẹda ba n ṣe ti ko ṣiwọ, bo pẹ titi, a mọ ni lọwọ jọjọ. Lọdun 1994 ni ọkunrin to waa di olori awọn Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ogun bayii, Kọmandanti Ahmed Abọdunrin, darapọ mọ ikọ naa gẹgẹ bii ọmọọṣẹ lasan, gẹgẹ bii ẹni to fẹẹ fara sin lai gbowo, nitori wọn ki i sanwo fawọn Sifu Difẹsi nigba kan, iṣẹ ilu ati iṣẹ ọfẹ ni wọn n ṣe.
Ọdun kẹrindinlọgbọn (26 years) rẹ ree lẹnu iṣẹ naa bayii, ọkunrin naa sọ iriri rẹ lẹnu iṣẹ yii fun akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun, ADEFUNKẸ ADEBIYI.
Kọmandanti Abọdunrin : Emi ni Kọmandanti Ahmed Abọdunrin, apaṣẹ ikọ Nigeria Security and Civil Defence Corps(NSCDC) nipinlẹ Ogun
ALAROYE: O ti pe ọdun kan bayii ti wọn ti gbe yin wa sipinlẹ Ogun gẹgẹ bii ọga patapata, ṣe iwa ọdaran pọ ju ni tabi o mọ niwọnba nipinlẹ yii?
Kọmandanti Abọdunrin: Ki i ṣe pe iwa ọdaran pọ nipinlẹ Ogun ju ti awọn ẹgbẹ rẹ lọ, nnkan to wa nibẹ ni pe ipinlẹ ẹnu iloro (Gateway State) fawọn ilu mi-in ni, ibẹ lawọn ajoji n gba wọle, ti wọn n gba jade. Eyi jẹ ki oriṣiiriṣii eeyan maa gba ipinlẹ Ogun kọja, ẹlomi-in ko tiẹ ni i lọ mọ, yoo taku sibi ni, ole si ni ẹlomi-in ninu wọn.
O tun waa jẹ pe ọpa epo to to kilomita ibusọ mọkandinlọgọrin (79KM) lo gba ipinle Ogun kọja, ọpa afẹfẹ gaasi naa gba ibẹ kọja, awọn onifayawọ naa n gba ibi kọja, gbogbo nnkan wọnyi le mu ki iwa ọdaran pọ niluu, o si wa lara awọn nnkan ti a n koju. Ṣugbọn ki i ṣe pe iwa ọdaran pọ nipinlẹ yii ju ti ipinlẹ mi-in lọ.
ALAROYE: Awọn agbegbe bii Arepo ti wọn ti maa n bẹ ọpa epo bẹntiroolu sinmi diẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, ọgbọn wo le da si i?
Kọmandanti Abọdunrin: Ko si ọgbọn ta a da si i ju iranlọwọ Ọlọrun ati ifọwọsowọpọ awọn araalu pẹlu ifọkansin awọn oṣiṣẹ mi. Bi mo ṣe sọ lẹẹkan, ibusọ ọpa epo nipinlẹ yii pọ, ṣugbọn ti Ọlọrun ba ran eeyan lọwọ, ti awọn araalu naa n fọwọ sowọ pọ, bo ṣe maa ri naa ree.
A ti jade lọ sọdọ awọn araalu, a ṣalaye fun wọn pe ọpa epo ti awọn ole n bẹ ko le ṣe ilu loore, nitori bi epo ba dapọ mọ omi, to ṣan lọ sibi tawọn eeyan wa, ina lo maa fa, ijamba ni yoo ṣẹlẹ. Nigba tawọn naa ko si fẹ wahala, bi wọn ba ti kẹẹfin awọn to n huwakiwa naa, wọn aa ta wa lolobo ni.
ALAROYE: Mo ṣakiyesi pe gbogbo ọran ni Sifu Difẹnsi n da si bayii, koda, ẹ n ri si ifipabanilopọ. Ṣe ijọba naa lo gbe iwọnyi le yin lọwọ ni abi ẹ kan n ran awọn ọlọpaa lọwọ ni?
Kọmandanti Abọdunrin?Ki i ṣe pe a n da si gbogbo iwa ọdanran bẹẹ yẹn naa, ohun ti ileeṣẹ wa wa fun ni lati daabo bo araalu ati dukia. Ṣe ẹ si mọ pe ẹni to ba ti n da aabo bo araalu ati dukia, ọta gbogbo ọdaran naa ni yoo jẹ.
Bi ẹ ba wo orukọ ileeṣe wa, NSCDC. Sikiọriti to wa ninu orukọ wa yẹn, aabo lo tumọ si, Difẹnsi ni lati gbogun ti iwa ọdaran, ẹni to ba si fẹẹ ṣe nnkan meji yii, ko si bi ko ṣe ni i koju bọ gbogbo iwa ọdaran to ba n waye. Iṣẹ eto aabo, bii iṣẹ oniṣegun ni. Ko si dokita ti ko ni i le fun eeyan loogun iba tabi inu rirun. Ṣugbọn to ba waa di pe aisan yẹn n le si i, nigba yẹn ni wọn a maa wa awọn akọṣẹmọṣe eka to jẹ mọ ohun to n ṣe ẹni yẹn.
Awọn iṣẹ kan wa ta a n pe ni Core Mandate, to jẹ iṣẹ tiwa gangan, iru ẹ ni ti ọpa epo tẹ ẹ sọ yẹn. To jẹ pe bawọn ologun ba mu wọn gan-an, wọn aa mu wọn wa fun wa ni, nitori wọn mọ pe awa la n ri si pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe dukia ijọba. Mi o ni i sọ pe nitori mi o ki i ṣe kọsitọọmu, ki n ri ẹni to n ṣe fayawọ ki n waa dakẹ, ma a mu un, ma a si fa a le awọn kọsitọọmu lọwọ ni, bi ọrọ eto aabo ṣe ri niyẹn.
ALAROYE: Nnkan ko fara rọ niluu lasiko yii, iwọde wọọrọwọ ti di wahala siluu lọrun. Ki lẹ ri si eyi?
Kọmandanti Abọdunrin: O ṣe ni laaanu pe iwọde lati fẹhonu han di ohun ti a n pa ara ẹni, ti wọn n pa ọlọpaa, ti wọn n dana sun ileeṣẹ ijọba ati adani, ko daa. Ko sohun to buru lati fi ẹhonu han, keeyan maa ba nnkan jẹ ni ko daa.
A gbagbọ pe awọn janduku lo gba kinni naa mọ awọn ọdọ lọwọ, ki i ṣe awọn ọmọ to fẹ daadaa fun ilu ni wọn n ṣe jagidijagan. A rọ wọn ki wọn jawọ nibẹ, niwọn igba tijọba ti ni awọn yoo ṣe ohun ti wọn n fẹ.
ALAROYE: Kin waa ni ajọ yin n ṣe si i bayii?
Kọmandanti Abọdunrin: Ipa ti Sifu Difẹnsi n ko lori ọrọ END SARS ko yatọ si eyi tawọn agbofinro yooku n ko. A n ri i pe awọn to n binu pada sile, kawọn eeyan yooku naa le maa ri ọna iṣẹ wọn lọ.
A ti da awọn eeyan wa sibi tawọn dukia ijọba wa, awọn dukia to jẹ bi ọwọ ibajẹ ba kan wọn, yoo ko wahala ba tẹru tọmọ ni. A si n ba wọn sọrọ pe ki wọn ma dan ibajẹ kankan wo, nitori ijọba ti loun yoo ṣe ohun ti wọn n fẹ.
ALAROYE: Sifu Difẹnsi naa n gbe ibọn bii ọlọpaa, bawo lẹ ṣe n lo ibọn tiyin?
Kọmandanti Abọdunrin: Bi ko ba di pe awọn ọta doju ibọn kọ wa, a ki i lo ibọn ni tiwa. Awa ki i lo ibọn ti ko ba jẹ pe ohun to n ṣẹlẹ lasiko yẹn gba pe ka lo o.
Bi a ba ri i pe ọdaran ṣetan lati yinbọn mọ wa, a le yinbọn mọ ọn lọwọ tabi lẹsẹ, ti ko fi ni i le yinbọn tiẹ. A si maa gbe e lọ sọsibitu.
Ọga wa patapata ta a n pe ni Alaaji Abdullahi Gana Muhammadu tiẹ sọ pe oun ko fẹẹ gbọ pe ibọn ṣeeṣi yin lọwọ wa rara ni. Nitori ki ọta ibọn too jade, o to ipele marun-un o. Bawo leeyan yoo ṣe waa to gbogbo ẹ pọ ti yoo ni o ṣeeṣi ni, ko gbọdọ ṣẹlẹ rara.
A dẹ tun maa n pada lọọ kẹkọọ si i nipa ibọn lilo, awọn ologun lo n kọ wa, awọn naa ni wọn si kọkọ ko ibọn bii ẹgbẹrun marun-un ta a kọkọ n lo fun wa.
ALAROYE: Iriri wo lẹ o le gbagbe ninu iṣẹ yin yii?
Kọmandanti Abọdunrin: Igba ti mo lọ si orilẹ-ede Philipine ni, ti mo foju rinju pẹlu awọn alakatakiti (Rebel). Wọn da bii eeṣin o kọku Boko Haram ta a ni nibi. Emi atawọn ẹgbẹ mi la lọọ kẹkọọ nibẹ, o ba mi lẹru gan-an nitori oriṣiiriṣii ofin ni wọn fun wa.
A o gbọdọ tẹju mọ wọn ju, a o gbọdọ ya fọto. Mo ri i pe bo ṣe jẹ pe inu igbo ni wọn n gbe to, wọn ni ọna to daa, wọn si n gbe ni alaafia niwọnba. Wọn ni aṣọ ologun tiwọn, wọn si ni awọn ibọn tiwọn.
Wọn ni kawa naa lọọ kọ ẹkọ lọdọ wọn nigba yẹn ni, ka ba wọn sọrọ pe kin ni wọn tun n fẹ lọwọ ijọba ti wọn n ba ja. O wú mi lori, mo si wo o pe iru nnkan bayii naa ṣee ṣe lọdọ wa o, pe ka ba awọn afẹhonu han tabi ajijagbara sọrọ pe kin ni wọn n fẹ. O kan jẹ pe awọn eeyan wa ki i nifẹẹ si ifikunlukun bẹẹ ni.
Iriri yẹn jọ mi loju pupọ to bẹẹ to jẹ ko si ọjọ ti mo ji ti mi o ki i ranti ẹ.
ALAROYE: Ọmọ ilu wo niyin, awọn ileewo lẹ si lọ?
Kọmandanti Abọdunrin: Ọmọ ilu Ìrẹ̀sì ni mi, nijọba ibilẹ Boluwaduro, nipinlẹ Ọṣun. Mo lọ sileewe pamari St. Judes, n’Irẹsi, ileewe Girama Baptist, mo tun lọ si Ẹdẹkun, ilu Irẹsi ni awọn ileewe yii wa, mo tun waa lọọ ṣe idanwo oniwee mẹwaa l’Oṣogbo Grammar School.
Mo lọ si Yunifasiti Eko (Unilag). Mo kẹkọọ nipa irisi ilẹ ati Aato (Geography and Planning). Mo lọ si Yunifasiti Ibadan, mo kẹkọọ nipele Masitaas, mo kọ nipa itọju ọmọniyan ati awọn ogunlende (Humanitarian and Refugee Studies).
Mo tun ṣe Masitaas mi-in lori ipẹtu-saawọ (Peace and Conflict Management). Mo tun lọ si Ọlabisi Ọnabanjọ Yunifasiti, mo ṣe Diploma ninu Kọmputa. Mo tun lọ si yunifasiti kan ni Thailand, iyẹn Chulalongkorn University, nipa ipẹtu-saawọ naa ni mo kẹkọọ le lori nibẹ, mo kẹkọọ ni Kofi Annan Yunifasiti, ni Ghana naa.
ALAROYE: Ki lo wu yin ninu iṣẹ Sifu Difẹnsi yii tẹ ẹ fi darapọ mọ wọn
Kọmandanti Abọdunrin: Mo maa n nifẹẹ si awọn ẹgbẹ to n fi ara sìn (Voluntary Clubs). Nigba ti mo wa nileewe girama, mo wa ninu ẹgbe ‘Boys Scout’.
Ni Yunifasiti, mo darapọ mọ ‘Man o war’, mo di alakooso ki n too kuro nileewe yẹn. Nigba ti mo ṣetan ni Unilag, mo maa n ri awọn Sifu Difẹnsi, o dẹ maa n wu mi lati darapọ mọ wọn lati sinru ilu, bi mo ṣe darapọ mọ wọn niyẹn ni 1994.
ALAROYE: Awọn ilu wo niṣẹ ti gbe yin de kẹ ẹ too de Abẹokuta?
Kọmandanti Abọdunrin: Mo ṣiṣe nipinlẹ Ọṣun, mo ṣiṣẹ nipinlẹ Kwara, mo ṣiṣẹ nipinlẹ Ọyọ, ipinlẹ Plateau naa ko gbẹyin.
Lẹyin iyẹn ni mo lọ si olu ileeṣẹ wa l’Abuja, lati ibẹ ni wọn ti gbe mi wa si Abẹokuta gẹgẹ bii ọga agba.
Iṣẹ yii ti gbe mi lọ si orilẹ-ede Cuba, Thailand, Philipines, mo lọ si Ghana naa, mo lọọ kọ ẹkọ mọ ẹkọ ni lawọn ilu naa.
ALAROYE: Imọran yin fawọn oṣiṣẹ Sifu jakejado
Kọmandanti Abọdunrin: Gbogbo iṣe ti kaluku ba n ṣe, ko lọọ nimọ nipa ẹ, ko ma jẹ pe o kan n wọṣọ lasan kiri. Ẹni to ba ti mọ iṣẹ tiẹ, ko ni i ba ẹlomi-in ja pe o n gba iṣẹ oun ṣe.
Tojo ba si n pa ikan ọrẹ, gbogbo wa pata leji n pa. Bi wahala ba ṣẹlẹ, kawọn iyawo tabi ọkọ wa too de, awọn oṣiṣẹ wa la maa kọkọ ri lati daabo bo wa. Fun idi eyi, ka maa ri ara wa, ọmọọṣẹ ati ọga bii pe ọkan naa ni wa.
Imọran kẹta ni pe ka ma ba ara wa jiyan, ifikunlukun lo daa. Iṣẹ aabo pọ ni Naijiria, a o ti i ṣe e debi kan, ko nilo ka maa ba ara wa ja, ifọwọsowọpọ lo n mu ile duro, ki kaluku sowo pọ, igba naa ni yoo daa. Ẹ ṣeun.