Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Bo ṣe jẹ pe kekere kọ ni iwa ọdaran ati jibiti to n ti ori foonu atawọn ẹka ayelujara ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii, ajọ NSCDC, iyẹn awọn Sifu Difẹnsi, nipinlẹ Ogun, ti da ẹka imọ ẹrọ igbalode ti yoo maa mu awọn to n fi ẹrọ lu jibiti kalẹ.
Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun 2020, ni wọn ṣi ẹka naa lolu ileeṣẹ wọn to wa labule Owu Dekudu, Kọbapẹ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, bẹẹ ni wọn si fun awọn oṣiṣẹ wọn to le ni igba (209) ni igbega si ipo tuntun.
Nigba to n ṣalaye lori ẹka naa, ọga agba Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ogun, Kọmandanti Hammed Abọdunrin, sọ pe agbekalẹ yii jẹ ọna kan pataki ti awọn fẹẹ maa fi gbogun ti iwa ọdaran lawujọ wa. O ni ida ọgọrin (80%) iwa ọdaran lo jẹ pe ori foonu lo ti n waye, ẹka tawọn da silẹ yoo si maa lo imọ ẹrọ lati tọpinpin awọn nọmba to ba lu jibiti, tabi hu iwa ọdaran, ti ọwọ yoo fi tẹ wọn nibikibi ti wọn ba wa.
Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun ti akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, ṣoju fun, o ni yoo dara bi awọn Sifu Difẹnsi ba le nawọ iru ọgbọn tuntun yii sawọn ẹka aabo mi-in lorilẹ-ede yii, nitori yoo jẹ ki iwa ọdaran dinkun lawujọ wa gidi.