Sikiọriti ji mọto ọga ẹ, nibi to ti fẹẹ ta a ni gbanjo ni wọn ti mu un

Faith Adebọla

 Ọwọ palaba gende-kunrin kan ti wọn gba gẹgẹ bii ọlọdẹ lati maa daabo bo dukia ati ọga rẹ ninu Esiteeti Ajao, to wa nipinlẹ Eko, ti segi, niṣe lọkunrin naa ji mọto ọga rẹ ọhun gbe, o fẹẹ lu u ta ni gbanjo, amọ ibi to ti fẹẹ ta a lọwọ ti ba a, taṣiiri si tu.

Lexus SUV bọginni olowo nla ni ọkọ ti wọn lo fẹẹ ta lowo pọọku ọhun, o si fẹẹ tete ṣe kinni naa ni yajoyajo, amọ ko ri i ṣe.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un yii, niṣẹlẹ naa waye, nigba ti wọn mu baba sẹkiọriti to dalẹ ọga rẹ ọhun, gbogbo ibeere ti ọga naa n beere ọwọ rẹ, niṣe ni afurasi ọdaran yii n wolẹ bii ole tilẹ mọ ba, ko le fesi kan. Ọga naa ṣọrọ pe:

“Gbogbo aye, ẹ wo ẹni to ji mọto mi gbe jade ni Ajao Estate, o fẹẹ lọọ ta a ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (N1.6m). Ọlọdẹ ti mo n sanwo fun, to n ṣiṣẹ sikiọriti fun mi ni o.

“Pẹlu gbogbo bi mo ṣe n bọ ọ, ti mo n fun un ni gbogbo nnkan, ti mi o si fiya owo-oṣu jẹ ẹ, ẹṣẹ wo waa ni mo tun ṣẹ o.
O waa fẹẹ lọọ ta mọto mi ni gbanjo. Iwọ lo waa wa mọto mi jade, o wọ ṣẹẹti funfun, ati ṣokoko ti ko balẹ. Oo mọ pe nigba to o waa gbe mọto yẹn, awọn aladuugbo mi ri ẹ, amọ nitori fila bẹntigọọ (face-cap) too de ko jẹ ki wọn da ẹ mọ daadaa.

“O fẹẹ lọọ ta mọto mi fun Ọgbẹni Ibrahim kan to n ta mọto lọna Airport Road, iyẹn lo pe lọọya ẹ wa, ki lọọya naa too ṣeto bi wọn ṣe f’ọlọpaa gbe e nigba to wa mọto mi d’ọdọ wọn’’.

A gbọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.

Leave a Reply