Jọkẹ Amọri
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ọlọpaa ṣafihan awọn mẹrin kan ti wọn ni wọn lọwọ ninu pipa ọrẹbinrin ọkan ninu wọn torukọ rẹ n jẹ Sọfiat.
Lasiko ti wọn n ṣafihan awọn ọdọmọkunrin naa nileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti n ka boroboro lori ipa ti wọn ko ninu iku ọmọbinrin ti wọn ge ọrun rẹ lati fi ṣoogun owo yii.
Meji ninu awọn ọmọ yii jẹwọ pe loootọ lawọn mọ nipa iku
ọmọbinrin naa. Wọn ni niṣe lawọn kọkọ yin in lọrun kawon
too pa a. Nibi ti awọn ti n dana sun ori naa ni wọn ti waa mu awọn.