Taofeek Surdiq, Ado Ekiti
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Ameh Sunday, to dọgbọn ji ara rẹ gbe, oun ati awọn ọrẹ rẹ yooku fẹẹ fi gba owo nla lọwọ ọga rẹ.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa tun kede pe ọwọ ti tẹ eeyan mẹta miiran ti wọn jẹ ọrẹ timọ-timọ Sunday. Orukọ awọn mẹta naa ni, Sunday Abah, Adejoh Friday ati Simeon Ojodomo.
Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, o ni ọkunrin kan, Taiwo Ọmọniyi, to n gbe ni adugbo Kajọla, n’Ikẹrẹ-Ekiti, to tun jẹ ọga Sunday, lo waa fi to wọn leti ni teṣan pe awọn ajinigbe ti ji oṣiṣẹ oun to n ṣiṣẹ ninu oko.
Ọkunrin yii ṣalaye fawọn agbofinro pe awọn agbebọn naa ti kan si oun, ti wọn si n beere aadọta miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ oṣiṣẹ oun naa.
Abutu fi kun un pe ni kete ti awọn ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni wọn bẹrẹ iwadii, ti wọn si mu ọkunrin yii nibi to fara pamọ si ni Ikẹrẹ-Ekiti.
O ni nigba ti iwadii ati itọpinpin bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ọkunrin yii jẹwọ pe oun ati awọn ọrẹ oun mẹta yooku lawọn jọ gbe eto ijinigbe naa kalẹ, ki awọn le fi gbowo lọwọ ọga oun.
Alukoro fi kun un pe gbogbo awọn ọdaran mẹta yooku ni wọn ti jẹwọ pe loootọ ni awọn jọ gbe eto ijinigbe ọrẹ awọn, Sunday, kalẹ, ki awọn le fi gbowo lọwọ ọga rẹ.
O fi kun un pe awọn ọdaran naa ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ni wọn ti wa ni atimọle awọn ọlọpaa to wa loju ọna Iyin-Ekiti, nibi ti wọn ti n gba atẹgun lọwọlọwọ. O sọ pe gbogbo awọn ọdaran naa ni yoo foju ba ile-ẹjọ lati foju wina ofin ni kete ti awọn agbofinro ba pari iwadii wọn lori ọrọ naa.