Monisọla Saka
Awọn agbofinro teṣan Ẹlẹrẹ, to wa lagbegbe Agege, nipinlẹ Eko, ti fi panpẹ ofin gbe ọkunrin oniṣowo, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47) kan, Mowobi Sunday, ti wọn si ti tun wọ ọ lọ sile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ sagbegbe Ọgba, niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko. Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin yii ni pe o ṣe oniduuro fun Banniya Babajide, lati le bẹrẹ iṣẹ nileefowopamọ First Bank, ṣugbọn to sa lọ lẹyin to ji miliọnu meji Naira owo banki ọhun.
Awọn ọlọpaa ṣalaye pe olujẹjọ ko si wahala yii nigba to gba lati ṣe oniduuro fọkunrin oṣiṣẹ banki to sa lọ yii lati gba iṣẹ sileefowopamọ naa lọdun 2019. Wọn ni lẹyin bii ọdun mẹrin to ti n ṣiṣẹ nibẹ ni Banniya ji miliọnu meji Naira, owo awọn ti wọn gba a siṣẹ.
Nigba ti Banniya fẹsẹ fẹ ẹ tan lawọn olupẹjọ ranṣẹ pe oniduuro lati wa ẹni to duro fun jade.
Igba to di pe ọkunrin yii ko ri Banniya mu wa ni olori ẹka to n mojuto eto inawo nileeṣẹ wọn, Ọgbẹni Akhanolu Solomon, lọọ fọrọ naa to awọn agbofinro leti ni teṣan wọn to wa ni Ẹlẹrẹ, lagbegbe Agege, nipinlẹ Eko. Loju-ẹsẹ ni ọga ọlọpaa yii ti ko awọn ikọ kan jọ, ti Insipẹkitọ Olubunmi Sunday ṣaaju, lati wa Ọgbẹni Mowobi jade.
Nibi kan tọkunrin naa lọọ fara pamọ si lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ẹ, ti wọn si tibẹ gbe e lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọgba, pẹlu ẹsun irọ pipa fun nnkan ti ko fi bẹẹ mọ nipa rẹ.
Ọlọpaa to n ṣoju ijọba ni kootu, DSP Ajayi Kẹhinde, ṣalaye ni kootu pe lati ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni olujẹjọ ti ṣẹ ẹṣẹ yii ni olu ileeṣẹ ile ifowopamọ First Bank of Nigeria, to wa lagbegbe Marina, ni Erekusu Eko.
O ṣalaye pe oniduuro ni Mowobi ṣe fun Banniya, lasiko to fẹẹ bẹrẹ iṣẹ ni banki ọhun, pẹlu ileri pe ki wọn mu oun fun iwakiwa abi igbesẹ yoowu ti ko ba bojumu ti ọkunrin naa ba gbe.
O ni nigba ti wọn waa sọ fun oniduuro yii lati wa oṣiṣẹ banki to duro fun jade, ti ọrọ di kọhọ, ti ko ri i mu wa, lawọn lọọ gbe e.
Agbefọba ni ijiya wa fun ẹṣẹ tọkunrin yii ṣẹ labẹ ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.
Ninu awijare rẹ niwaju adajọ, Mowobi loun ko jẹbi. Eyi lo mu ki adajọ kootu ọhun, Onidaajọ E. K. Kubainje, faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), silẹ fun un, pẹlu oniduuro kan.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii. Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn da olujẹjọ duro si ọgba ẹwọn Ikoyi, nipinlẹ Eko, titi ti ọrọ beeli rẹ yoo fi yanju.