Florence Babaṣọla, Osogbo
Ọkan lara awọn ajijagbara fun iran Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, ti sọ pe ko si ẹni naa to le da Yoruba duro mọ lori ipinnu wọn lati kuro lara orileede Naijiria, ki wọn si da orileede tiwọn ni.
Lasiko to n sọrọ nibi iwọde lori Iṣọkan ilẹ Yoruba to waye niluu Oṣogbo lọjọ Àbámẹ́ta, Satide, opin ọsẹ yii lo sọrọ naa ni Feeedom Park. Sunday Igboho sọ pe iya to jẹ iran Yoruba labẹ idari awọn Fulani ti to gẹẹ.
Igboho, ẹni to de pẹlu ogunlọgọ ero lẹyin rẹ ni nnkan bii aago meji ọsan ku iṣẹju mẹwaa ṣalaye pe gbogbo ipo agbara to wa lorileede yii patapata ni awọn Fulani n dari, eyi to tumọ si pe wọn ko ni erongba rere kankan fun awọn iran to ku lorileede yii.
O dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, fun anfaani to fun wọn lati ṣewọde naa, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ awọn lọbalọba, bẹrẹ lati ori Ọọni, Alaafin, Ataọja atawọn to ku, fun atilẹyin wọn.
O waa rọ awọn ọmọ Yoruba lati wa niṣọkan, ki wọn mọ pe a ki i ri ẹfọn ta lẹẹmeji, ki wọn sọrọ soke pẹlu ohun kan pe o ti to gẹẹ.