Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ariwo, “ẹ dakun, ẹ gba mi, Igala ni mo fẹẹ pa, igbe eeyan ni mo gbọ” ni baba ọdẹ kan, Alagba Olubusade Sunday, fi bọnu lẹyin to ṣeesi yinbọn pa ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Thankgod Ọmọle, laarin oru, nigba to n ṣọdẹ kiri, to kọju ibọn si eeyan, to si ro pe ẹran igala ni.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla yii, niṣẹlẹ naa waye lagbegbe kan ti wọn n pe ni Onikẹrosin, n’ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo.
Ọga ọlọpaa kan to ṣalaye ọrọ naa fun akọroyin wa, ṣugbọn ta a forukọ bo laṣiiri, sọ pe ọmọ abule kan naa ni Alagba Sunday ati Thankgod, koda, o ni ile awọn mejeeji ko fi bẹẹ jinna sira wọn rara.
Ọga ọlọpaa ọhun ni nibi ti Thankgod ti bọ ara silẹ to n wẹ ninu odo ni baba ẹni ọdun mẹrindinlọgọta naa ti rọ ibọn to fi n ṣọdẹ bo o, leyii to ṣokunfa iku rẹ lẹsẹkẹsẹ, o ro pe ẹran Igala ni.
O ni aake ati igbà ti wọn fi n kọ ọpẹ ti wọn ba lẹgbẹẹ odo, nibi ti oloogbe ọhun ko wọn si, lo jẹ kawọn agbofinro mọ pe iṣẹ akọpẹ wa lara iṣẹ oojọ to yan laayo ninu abule naa.
Baba ọlọdẹ ọhun funra rẹ lo lọ si teṣan awọn ọlọpaa to wa ni Bọlọrunduro, eyi ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.
ALAROYE gbọ pe o ṣee ṣe ki baba ọhun foju bale-ẹjọ laipẹ, pẹlu bi wọn ko ṣe ti i ri ọrọ naa yanju nitubi-inubi laarin awọn ẹbi oloogbe ati Alagba Sunday.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun akọroyin wa nigba ta a pe e sori aago, bo tilẹ jẹ pe o sọ fun wa pe oun ko ti i le sọrọ pupọ nipa rẹ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ.