Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo aye lo n fi ijọba ipinlẹ Ọyọ atawọn alaṣẹ UCH, iyẹn ileewosan ijọba apapọ to wa niluu Ibadan ṣe yẹyẹ nigba ti owo nla kan dija silẹ laarin wọn.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020 yii, ni Kọmiṣanna feto iṣuna nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Akinọla Ojo, sọ fawọn oniroyin pe owo to le ni biliọnu meji Naira (N2.77b) nijọba oun ti na lori igbogun ti itankalẹ arun Korona ati itọju awọn to lugbadi arun naa bayii.
Kọmiṣanna Gomina Makinde yii sọ pe ninu owo yii, miliọnu mejidinlọgọfa Naira (N118m) nijọba awọn pin kan ileewosan UCH lati fi gbọ bukaata ti wọn n gbọ lori ayẹwo ati itọju awọn eeyan lori ajakalẹ arun ọhun.
Ṣugbọn awọn alakooso UCH ko ti i jẹ ki iroyin yii tutu ti wọn fi pariwo sita, wọn ni ijọba ko fawọn lowo kankan, ati pe gbogbo akitiyan awọn lori ayẹwo ati itọju awọn alarun Korona, awọn kan n ṣe e gẹgẹ bii ojuṣe awọn si igbe aye alaafia awọn araalu ni, ki i ṣe pe ẹnikẹni n fun awọn lowo iṣẹ naa lọtọ.
Ninu atẹjade ti Alukoro ileewosan ijọba apapọ yii, Ọgbẹni Toye Akinrinọla, fi sita, lo ti ni “A gbọ ọ ninu iroyin pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fun ileewosan UCH ni miliọnu mejidinlọgọfa Naira gẹgẹ bi Ọgbẹni Akinọla Ojo ti i ṣe kọmiṣanna feto iṣuna ṣe sọ.
“Ọrọ naa ru wa loju diẹ, iyẹn la ṣe kan si awọn to yẹ ka kan si ninu awọn to n ṣejọba ipinlẹ Ọyọ lati beere alaye lori ẹ. Ṣugbọn wọn n sọ ọ bii ẹni pe ẹka imọ iṣegun oyinbo (College of Medicine) ti Yunifasiti Ibadan ni wọn fun lowo naa, ohun to si fẹẹ da aigbọra-ẹni-ye silẹ niyẹn nitori ẹka imọ iṣegun oyinbo ti Yunifasiti Ibadan yatọ sileewosan UCH.
“Gbogbo iranlọwọ ta a (UCH) ri gba latọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ju ọtalerugba-odin-mẹwaa (250) ohun eelo idaabobo lori ajakalẹ arun Korona ti wọn fun wa laipẹ yii lọ. Ṣugbọn pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fun wa lowo iranwọ kan lori ọrọ Korona, irọ, ko si ohun to jọ ọ.
“Oludari agba ileewosan UCH, (CMD, Ọjọgbọn Jesse Ọtẹgbayọ) jẹ ọkan ninu awọn adari igbimọ to n gbogun ti ajakalẹ arun Korona, nipa bẹẹ, ko si bi ijọba ṣe maa fun UCH niru owo bẹẹ ti wọn ko ni i mọ nipa ẹ.”
Bi iroyin ọrọ yii ṣe jade sita fun gbogbo aye gbọ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i bu ẹnu atẹ lu ijọba Gomina Makinde, wọn ni ki lo de ti wọn n pa iru irọ nla bẹẹ, irọ ti ko le bo wọn lẹyin ẹsẹ. Wọn si n reti ọrọ ti aṣoju ijọba tabi Gomina Makinde funra rẹ yoo sọ lati ko ọrọ wọn nipa ileewosan UCH jẹ.
Ṣugbọn niṣe nijọba tun sọrọ pẹlu igboya pe loootọ lawọn na owo nla naa fun awọn oṣiṣẹ ẹka kan nileewosan UCH lati gbọ bukaata wọn lẹnu iṣẹ.
Akọweeroyin Gomina Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa sọ ninu atẹjade to tun fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja pe ijọba ti ṣetan lati gbe ẹri jade sita fun gbogbo aye ri lati mọ pe loootọ lawọn fi miliọnu mejidinlọgọfa Naira ran ileewosan ijọba apapọ naa lọwọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ẹka to n ri si itọju awọn arun to ni i ṣe pẹlu kokoro aifojuri nileeewosan UCH la nawo yẹn fun lati maa fi tọju awọn to lugbadi arun Korona nipinlẹ yii.
“Oludari agba ileewosan UCH, Ọjọgbọn Jesse Ọtẹgbayọ, funra rẹ lo fi akọsilẹ awọn ohun eelo ti ẹka yii nilo ṣọwọ si ijọba nigba kan, ohun eelo fun eto ilera to jẹ miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira nijọba wa si ra lẹẹkan naa nigba naa.
“Diẹ ninu awọn ohun eelo ta a tun ra fun awọn olutọju alarun Korona nigba naa lọhun-un ni bata amunidórúnkún, awò ojú, aṣọ gbagẹrẹ to maa n bo awọn olutọju alarun Korona ni gbogbo ara. Iru awọn inawo bayii atawọn inawo min-in bẹẹ si ti na ijọba wa to miliọnu lọna ọgbọn (N30m) Naira.
“Lara awọn nnkan ta a na owo yooku le lori ni ipese awọn ohun eelo fun ayẹwo ẹjẹ lati mọ awọn to ti ni kokoro arun Korona lara. Bẹẹ nijọba wa n fun awọn oṣiṣẹ ẹka itọju arun kokoro aifojuri to jẹ ẹka kan nileewosan UCH lowo ajẹmọnu lori iṣẹ ti wọn n ṣe lasiko ajakalẹ arun yii.”
Ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewosan yii ti sẹ kanlẹ, wọn lawọn ko jẹ iru anfaani owo nla bẹẹ lọdọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ibi ti wọn ba nawo si gan-an ni ki wọn sọ.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ, agbẹnusọ ileewosan UCH, Ọgbẹni Toye Akinrinọla tun sọ ọ pẹlu igboya pe “bẹẹ ni, UCH ko gbowo kankan lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ. A ti sọ bẹẹ tẹlẹ ninu atẹjade kan ta a fi sita. Ohun ta a si sọ naa ko yipada.”
Ni bayii ti agbọn n sẹ, ti oyin paapaa si n sẹ, to si jẹ oju oloko lo wu gbandu mọ ọn lagbari yii, ẹni to n purọ ninu ijọba ipinlẹ Ọyọ atawọn alaṣẹ ileewosan UCH, Ibadan lẹnikan ko ti i mọ bayii.
Oro di hunnnnn !