Ta o ba ṣọra, ijọba maa ta epo bẹntiroolu ni ẹẹdẹgbẹta naira kọdun yii too pari-Falana  

Faith Adebọla, Eko

Agba amofin, ati ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Oloye Fẹmi Falana, ti kegbajare pe aṣiri kan ti tu soun lọwọ nipa erongba ati igbesẹ ijọba to wa lode ti Ọgagun-fẹyinti Muhammadu Buhari n tukọ rẹ yii, o ni wọn maa ta epo bẹntiroolu ni ẹẹdẹgbẹta naira (#500) tabi ko ju bẹẹ lọ, kọdun 2021 ta a wa yii too kogba sile.

Ilu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ni Falana ti sọrọ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, nibi apero kan ti wọn ṣe lati fikun lukun lori boya ẹgbẹ oṣelu mi-in le wa yatọ sawọn to ti wa nilẹ tẹlẹ, wọn pe akọle apero naa ni: “Igba ọtun ṣee ṣe ni Naijiria” (New Nigeria is Possible).

Gẹgẹ bii olubanisọrọ pataki nibi apero naa, Amofin agba Falana ṣe atupalẹ bijọba to wa lode yii ṣe n fowo le ori epo bẹntiroolu ni gbogbo igba, o si ṣe ifiwera eyi pẹlu awọn iṣakoso to ti kọja ki Buhari too de.

O ni ijọba Buhari yii ko loootọ, irọ ni wọn n pa faraalu nipa owo iranwọ ti wọn lawọn n fi kun owo epo bẹntiroolu, o ni ko tiẹ yeeyan mọ bayii boya wọn yọ owo iranwọ kuro tabi wọn ṣi n fi kun un, tori ‘a ti yọ ọ, a ti fi kun un’ nijọba n pariwo lojoojumọ.

“Loṣu Sẹtẹmbaọdun to kọja, ijọba yii kan naa kede naira mejidinlaaadọsan-an (#168) lawọn maa ta epo bẹntiroolu tori awọn ti yọwọ patapata ninu afikun owo-ori epo. Lonii, ohun tijọba tun n sọ ni pe owo-epo n lọ si okoolerugba naira ati mẹwaa (#230), tori awọn fẹẹ yọ afikun owo-ori epo kuro ni.

“Ṣugbọn, ẹ jẹ ki n ta yin lolobo kan, ta o ba ṣọra, ẹẹdẹgbẹta naira nijọba yii maa ta epo bẹntiroolu kọdun yii to pari. Ki i ṣe pe mo n mefo o, erongba ati eto ti wọn ti ṣe silẹ ni.”

Falana ni iṣoro to n ba orileede yii finra, paapaa lori ọrọ aabo to mẹhẹ, owo naira to di pọ-n-tọ lọja agbaye, airiṣẹ ṣe to burẹkẹ si i, ijọba ti o mọyan lori to wa lati ijọba ibilẹ si tipinlẹ titi dori apapọ, ọrọ naa ti di ailaṣọ lọrun paaka, to to nnkan apero fawọn ọmọ eriwo.

O ni arun oju ni, o han kedere pe awọn ọbayejẹ ọjẹlu kan ti fẹsẹ rinlẹ sara ijọba apapọ, ile agbara ni wọn mori mu si, ti wọn o si bikita bijọba yii ba le faya ko faya.

CAPTION

 

Leave a Reply