Tẹ ẹ ba fẹẹ ṣe pati l’Ọṣun, eyi lawọn nọmba tẹ ẹ gbọdọ pe kẹ ẹ too dana ariya

Florence Babaṣọla

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede awọn ofin titun bayii lati dena itankalẹ arun Koronafairọọsi. Ninu atẹjade kan ti akọwe ijọba, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, fi sita lo ti sọ pe ko si inawo to gbọdọ ni ju eeyan aadọta lọ, bẹẹ ni ileejọsin ko gbọdọ ṣesin ju wakati meji lọ, ko si si iṣọ-oru tabi isọji itagbangba mọ.

O ni ṣọọsi tabi mọṣalaaṣi to ba tapa si ofin idena Korona yoo san ẹgbẹrun lọna aadọta naira (#50,000), nigba ti awọn ileetura tabi ile igbafẹ to ba ta ko ofin ijọba yoo san ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira (#250,000).

Oyebamiji fi kun ọrọ rẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade nile lati aago mẹwaa alẹ titi di aago marun-un idaji, bẹrẹ lati ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii, bẹẹ ni awọn oṣiṣẹ lati ipele ikejila sisalẹ yoo maa ṣiṣẹ wọn nile.

Gbogbo awọn ileetaja nla nla ni wọn gbọdọ pọn ibomu lilo ni dandan fun ẹnikẹni to ba fẹẹ ra nnkan lọdọ wọn. Ẹnikẹni to ba si n rin laarin ilu lai lo ibomu yoo ri pipọn oju ijọba ati pe ọfẹ ni ayẹwo arun Korona nibikibi ti wọn ba ti fẹẹ ṣe e.

Ni ti awọn ọlọkada, ijọba ni wọn ko gbọdọ gbe ju eeyan kan lọ, bẹẹ ni awọn onikorope ko gbọdọ gbe ju eeyan mẹrin lọ. Bakan naa ni awọn oludasilẹ ileewe gbọdọ tẹle ofin ati alakalẹ tijọba gbe kalẹ.

Oyebamiji sọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣenawo gbọdọ gba aṣẹ lọwọ ijọba nipasẹ awọn nọmba yii: 08135081156 tabi 08187187678.

Leave a Reply