Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti fi tẹgbọn-taburo kan, Abdullateef ati Yusuf Adekanye, sọgba ẹwọn to wa ni Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe wọn lọọ hu oku baba wọn, Zakarya Adekanye, lati fi ṣoogun owo.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lo wọ awọn ọmọ iya meji naa lọ siwaju ile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, fẹsun pe wọn lọọ hu oku baba wọn to ti ku lati ọdun 2012, ti wọn si ko gbogbo egungun rẹ lati fi ṣoogun owo, leyii to ta ko abala kẹtadinlọgọrun-un (97) ati igba-le-mẹrindinlọgbọn (206) ninu iwe ofin ilẹ wa.
Agbefọba, Moshood Adebayọ, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn tẹgbọn-taburo ọhun lọ si agboole wọn to wa ni Agba- Akin, niluu Ọffa, ti wọn si lọọ hu oku baba wọn, Zakarya Adekanye, ti awọn mọlẹbi ko mọ si i, fun idi eyi, iwa ọdaran ni wọn hu.
Awọn afurasi ọhun sọ fun ile-ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn. Onidaajọ Mohammed Adams paṣẹ pe ki wọn gbe awọn mejeeji lọ si ọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, o sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.