Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn ọmọ iya meji kan ti wọn jẹ tẹgbọn-taburo, Ibrahim Umar ati Musa Umar, ti n rewele bayii pẹlu bi wọn ṣe taari wọn lọ sile-ẹjọ Majistreeti kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, fẹsun pe wọn ji maaluu ọga wọn kan, Awoyẹmi Emmanuel, to n lọ bii mẹẹẹdọgbọn (25), ko lọ.
Agbefọba, Ayeni Gbenga, sọ fun ile-ẹjọ pe Awoyẹmi Emmanuel, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa pe Ibrahim Umar loun kọkọ gba pe ko maa ba oun da maaluu, nigba to ya loun tun pe awọn aburo rẹ meji, Musa Umar ati Aliyu, to ti sa lọ bayii, ti wọn si jọ n da maaluu to le ni ọgọrun-un kan niye. Ṣugbọn awọn eeyan naa gbimọ-pọ, wọn si ji mẹẹẹdọgbọn ninu maaluu naa, wọn si lọọ ta wọn ni gbanjo, lẹyin eyi ni wọn sa lọ si abule Atipo, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.
Ayẹni waa rọ ile-ẹjọ lati ma gba beeli awọn olujẹjọ yii, o ni ki wọn ju awọn mejeeji tọwọ tẹ sahaamọ titi ti iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.
Onidaajọ Ibrahim Dasuki, gba beeli awọn afurasi ọhun, o sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.