Pako bayii lawọn ọmọ iya meji kan, Ayọọla Timilẹhin, Oluṣọla Timilẹhin atawọn ọre wọn n wo bayii ninu akolo ajọ EFCC lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn. Adugbo kan ti wọn n pe ni Alaka Ẹlẹbu lọwọ ti tẹ wọn niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Ọrọ ti Ọgbẹni Dele Oyewale, agbẹnusọ fun ajọ ọhun, sọ ni pe awọn eeyan kan lo ta awọn lolobo irufẹ igbe-aye ijẹkujẹ tawọn eeyan ọhun n gbe lai ni iṣẹ gidi kan pato lọwọ, lo fa a ti wọn fi ke sawọn.
Awọn mi-in tọwọ tun tẹ pẹlu awọn ọmọ iya meji yii ni, Temitọpẹ Kumuyi, Babatunde Oyelakin, ati Ọlanrewaju Ibrahim. Gbogbo awọn ọmọ tọwọ tẹ yii, ni wọn sọ pe ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ọgbọn ọdun lọ.
Awọn irinṣẹ ti wọn ka mọ wọn lọwọ niwọnyi, erọ kọmputa alagbeeka, awọn foonu olowo iyebiye, onlu kan to je ti ẹka iṣuna owo ti ileewe Queensland University’s School of Medicine, lorilẹ-ede Australia ati mọto ayọkẹlẹ mẹrin.
Oyewale ti sọ pe ile-ẹjọ lawọn ọmọkunrin naa yoo ti ṣalaye ohun ti wọn ri lọbẹ ti wọn fi gaaru ọwọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii awọn.