Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Okobo awọn ọre meji yii, Aṣimiyu Temitọpẹ ati Oyewumi Biọdun, ko bimọ sitosi nidii iṣẹ okoowo ole ti wọn yan laayo o, ipinlẹ Delta lọhun-un ni wọn ti lọọ ji mọto onimọto gbe, ni wọn ba gbe e wa si Ekiti lati waa ta a. Asiko naa ni wọn ko sọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti to n gbogun ti awọn to n ji ọkọ gbe, ni wọn ba mu wọn ṣinkun. Wọn ṣi wa lakata awọn agbofinro ti wọn n ṣẹju pako bii maaluu to rọbẹ.
Gẹgẹ bi Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣe sọ, o ni ẹnikan tawọn ko mọ lo ṣadeede pe awọn pe awọn ri afurasi meji kan ni agbegbe Agric-Ọlọpẹ, l’Ado-Ekiti, ti wọn n wa ọkọ bọọsi kaakiri adugbo naa, ti awọn si fura si wọn pe ole ni wọn.
O ṣalaye pe ni kete tawọn gba ipe naa ni ẹka to n gbogun ti jiji ọkọ ti olu ileeṣẹ wọn wa ni Ado-Ekiti gbera, ti wọn si lọ si agbegbe naa, nibi ti ọwọ wọn ti tẹ awọn afunrasi meji naa.
O fi kun un pe nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, iwadii fihan pe ipinlẹ Delta ni wọn ti wa, nibi ti wọn ti n ṣe iṣẹ buruku wọn niyi, ṣugbọn wọn fẹẹ wa si nla ipinlẹ Ekiti lati wa maa ṣe iṣẹ ọkọ jiji ti wọn yan laayo yii.
Lasiko iwadii siwaju si i, ni aṣiri tu pe lati ipinlẹ Delta ni wọn ti ji ọkọ bọọsi ti wọn ka mọ wọn lọwọ, ti wọn si gbe e wa sipinlẹ Ekiti.
Bakan naa ni wọn ri aṣọ ọlọpaa gba lọwọ ọkan lara awọn ọdaran meji naa, iyẹn Aṣimiyu Temitọpẹ, o si jẹwọ pe aṣọ naa loun maa n wọ ti oun fi maa n jale.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Dare Ogundare, gboṣuba fun awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, aatawọn eeyan ipinlẹ naa pẹlu bi wọn ṣe fọwọsọwọpọ pẹlu awọn ọlọpaa lati maa ta wọn lolobo lori awọn ọdaran ti wọn ba kẹẹfin.
Kọmiṣanna tun waa rọ awọn eeyan naa lati maa ke sawọn agbofinro bi wọn ba ti ri awọn ajeji lagbegbe wọn.
O fi kun un pe awọn ọdaran meji ti ọwọ tẹ naa yoo pada si ipinlẹ Delta, ki wọn le foju wina ofin.