Tijani, ayederu afaa to n lu awọn obinrin ni jibiti l’Ondo ti ha

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ayederu aafaa kan, Waliu Tijani, lọwọ palaba rẹ ṣegi laaarọ ọjọ Ẹti, Furaide ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, nibi to ti n gbiyanju lati lu awọn obinrin Musulumi kan ni jibiti laduugbo Ebenezery, Ayeyẹmi, niluu Ondo.

ALAROYE gbọ pe lati bii ọsẹ kan sẹyin lọkunrin to pe ara rẹ ni ojisẹ Ọlọrun naa ti n lọọ ba awọn abilekọ meji kan ninu ṣọọbu itaja wọn to wa ni Ebenezery, to si n riran si wọn lai mọ pe iyawo aafaa Musulumi gidi lawọn mejeeji.

Ọkan ninu wọn to b’ALAROYE sọrọ ṣalaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji ọhun ti waa ba oun pẹlu tẹsibiyu lọwọ rẹ ki oun le gbagbọ pe aafaa Ọlọrun gidi ni i ṣe.

O ni ṣuga lo sọ pe oun waa ra lọjọ akọkọ to wa, lẹyin to raja ọhun tan lo ni o bẹrẹ si i riran soun, to si ni oun gbọdọ ra okete pẹlu awọn nnkan etutu mi-in ki ọrọ aye oun too le loju.

O ni oun fun un ni ẹgbẹrun kan Naira ninu owo to beere lọwọ oun, lati igba naa lo ni o ti n pada wa si ṣọọbu oun lemọlemọ lati sin owo etutu yooku to fẹẹ gba lọwọ oun.

Obinrin yii ni ọwọ palaba afurasi onijibiti naa ṣegi laaarọ ọjọ naa pẹlu bi ọkọ oun ṣe rin si asiko igba to tun pada wa lati sin owo iṣẹ to ni oun fẹẹ ṣe fun oun.

Ninu ọrọ tirẹ to ba wa sọ, Alaaji Adebayọ Alao to jẹ ọkọ obinrin naa ni ki i ṣe pe oun fẹẹ ba afurasi ọhun ja nigba ti oun ka a mọ ibi to ti n lu iyawo oun ni jibiti.

Agbalagba aafaa to jẹ olori mọṣalaasi kan to wa laduugbo naa ni gbogbo bo ṣe n wa ni iyawo oun n ṣalaye fun oun, bẹẹ ni oun ko si ṣe bii ẹni pe oun ni ọkọ obìnrin naa nigba ti oun kọkọ yọju si i.

O ni bo ṣe ri oun lo gba tẹsibiyu rẹ mu girigiri, to si bẹrẹ adura lakọtun, lojiji lo ni o deedee yi ẹyin pada biri, to si fẹẹ maa sa lọ ki oun too pe e pada lati fọrọ wa a lẹnu wo.

Afurasi ọhun lo ni ko ri esi gidi kan fun oun lori gbogbo ibeere toun n beere lọwọ rẹ nipa ibi to ti kọ iṣẹ aafaa, ẹni to kọ ọ niṣẹ ati mọṣalasi to ni oun lọ.

Dipo ti iba si fi dahun awọn ibeere naa, ṣe lo kọju ija si Alaaji ọhun, to si fa agbada to wọ sọrun ya pẹrẹpẹrẹ. Eyi lo bi awọn oluworan kan ninu ti wọn fi suru bo o, ti wọn si po ẹkọ iya diẹ fun un mu kawọn agbaagba tọrọ ṣoju wọn too gba a silẹ lọwọ wọn.

Nigba ta a n fi ọrọ wa Tijani funra rẹ lẹnu wo, alaye to ṣe fun wa ni pe suga loun waa ra lọwọ iyawo aafaa naa ti awọn fi mọ ara. Obinrin ọhun funra rẹ lo ni o bẹ oun lati ba a ṣe adura ki ija to wa laarin oun ati ọkọ rẹ le pari.

O ni loootọ loun kewu, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe pe oun fi n ṣiṣẹ ṣe, iṣẹ igi gẹdu gige lo ni oun n ṣe lọwọlọwọ. Tijani ni ẹgbẹrun kan Naira pere loun ṣi gba lọwọ rẹ gẹgẹ bii owo adura.

Ọkunrin onijibiti ọhun ni wọn ni ko ti i rowo gba lọwọ obinrin keji kọwọ too pada tẹ ẹ, bakan naa ni wọn tun ba tẹsibiyu kan, igo ogogoro nla kan to kun dẹnu ati tọọsi kan ni ikawọ rẹ.

Awọn ẹsọ Amọtẹkun to n mojuto eto aabo nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo ni wọn pe lati waa gbe ọkunrin naa lọ si ọfiisi wọn fun ifọrọwanilẹnuwo.

Leave a Reply