Timothy Adegoke: Awọn olupẹjọ pe ẹlẹrii mẹjọ, awọn olujẹjọ ni awọn ko ni ẹjọ kankan lati ro

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin ti agbẹjọro olupẹjọ ninu ẹsun ti wọn fi kan Dokita Rahman Adedoyin to ni ileetura Hilton, ni Ileefẹ atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa, Barisita Omosun, ti pe awọn ẹlẹrii mẹjọ ni awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ sọ pe awọn ko ni ẹjọ kankan lati ro lori awọn ẹsun naa.

Timothy Adegoke, akẹkọọ Fasiti Ifẹ, lo ku sileetura Hilton lọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja, eleyii lo si yọri si bi wọn ṣe mu Adedoyin, Adedeji Adeṣọla (23), Magdalene Chiefuna (24), Adeniyi Aderọgba (37), Oluwale Lawrence (37), Oyetunde Kazeem (38) ati Adebayọ Kunle (35).

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, nigbẹjọ naa bẹrẹ niwaju adajọ agba fun ipinlẹ Ọṣun, Onidaajọ Adebọla Adepele-Ojo. Awọn olupẹjọ si ti pe mọlẹbi oloogbe kan, iyawo rẹ, ẹgbọn rẹ, IPO ọlọpaa kan l’Oṣogbo ati l’Abuja, oṣiṣẹ ajọ wolewole ati dokita to ṣayẹwo si oku lati jẹrii.

Nigba ti igbẹjọ naa tun waye ni ọjọ Aje, Mọnde, Ọmọsun pe ẹlẹrii kẹjọ, iyẹn, DSP ọlọpaa kan, Samuel Odeh, ẹni to mu ayẹwo kan (forensic analysis) ti wọn ṣe lọdọ wọn wa si kootu. Lẹyin ẹri rẹ ni Omosun sọ pe awọn ko ni ẹlẹri kankan mọ.

Awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Yusuf Ali SAN ati K. K. Eleja SAN; Muritala AbduRasheed SAN, Rowland Otaru SAN, ati Okon Ita, sọ fun ile-ẹjọ lẹyin ti wọn forikori pe awọn onibaara awọn ko ni ẹjọ kankan lati jẹ lori ọrọ naa.

Nitori naa, Onidaajọ Adepele Ojo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ti a wa yii lati gba akọsilẹ gbogbo awọn agbẹjọro.

Ṣaaju, laarin ọsẹ to kọja ni Dokita akọṣẹmọṣẹ nipa ayẹwo si ara oku (Consultant Pathologist), to n ṣiṣẹ pẹlu ileewosan UNIOSUNTHC, Oṣogbo, Dokita Waheed Akanni Oluogun, ti sọ pe ninu ayẹwo ti oun ṣe si oku Timothy Adegoke, ko si aisan kankan lara rẹ titi digba to ku.

Leave a Reply