Faith Adebọla
Agba ọjẹ oloṣelu ilu Eko ati adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nni, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sabẹwo pataki si Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, nile rẹ to wa nile ijọba, l’Abuja.
Ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn yii, ni Tinubu kanlẹkun ile Aarẹ, tiyẹn si gba a lalejo.
A gbọ pe bi Bọla ṣe de ọdọ Buhari ni wọn ti wọle si yara alejo, ti wọn si tilẹkun mọri ṣepade fun bii ogoji iṣẹju, wọn ko faaye gba oniroyin kan nipade ọhun.
Amọ lẹyin ipade naa, Tinubu ba awọn oniroyin sọrọ nile ijọba, o ni koko pataki ipade toun ṣe pẹlu Aarẹ ni lati dupẹ lọwọ Buhari fun bo ṣe pọn oun le, to ṣabẹwo sọdọ oun nigba toun n gba itọju lọwọ laipẹ yii niluu London, lorileede United Kingdom, latari ojugun to dun oun toun lọọ ṣiṣẹ abẹ si.
O ni eeyan daadaa ni Buhari, ọmọluabi ni, Olori to si ṣe e mu yangan ni, tori o kaaanu oun, o si bikita nipa awọn eeyan.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni Tinubu ṣe iru abẹwo yi kan naa si Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, l’Abuja, ti wọn si jọọ tilẹkun mọri sọrọ bakan naa.