Ọrẹloluwa Adedeji
Lati mu ki erongba rẹ lati wọle ipo aarẹ to n bọ lọdun 2023, wa si imuṣẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Kogi, Yahya Bello, ti wọn jọ dije lasiko eto idibo abẹle lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii.
Tinubu, ẹni to ṣapejuwe Bello gẹgẹ bii ọmọ rẹ sọ pe oun gboriyoin fun un pẹlu bo ṣe ko awọn ọdọ mọra, ti wọn si ṣugbaa rẹ lasiko eto idibo abẹle naa.
Ninu ọrọ tiẹ, gomina Kogi ni pẹlu abẹwo yii, oun ti ko gbogbo awọn alatilẹyin oun ti wọn n polongo ibo fun oun fun Tinubu, bẹẹ loun si tun yọnda ile ẹgbẹ ti oun n lo fun ipolongo ibo niluu Abuja fun un. O waa ṣeleri atilẹyin fun gomina Ọyọ tẹlẹ naa pe oun yoo ṣe atilẹyin fun un.
Yahya ni eto idibo abẹle ti waye, o si ti lọ, ni bayii, oun yoo jade si igboro lati ko awọn ọdọ sodi fun ipolongo rẹ lati ṣe atilẹyin fun un ko le baa rọwọ mu lasiko eto idibo to n bọ.
Bakan naa ni Gomina Eko tẹlẹ naa tun ṣabẹwo si Rotimi Amaechi ti wọn jọ dije dupo aarẹ lasiko eto idibo abẹle naa. Ile rẹ to wa niluu Abuja lo ti bẹ ẹ wo, to si beere fun ifọwọsowọpọ rẹ.
Nigba to n ṣalaye nipa ipade to waye laarin oun ati Tinubu, gomina Rivers tẹlẹ naa ṣeleri atilẹyin fun Tinubu, o ni awọn yoo jọ ṣiṣẹ papọ lati ri i pe ẹgbẹ APC jawe olubori lasiko eto idibo to n bọ.