Tinubu ṣabẹwo sọdọ Babangida

Adewumi Adegoke

Oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti ṣabẹwo si aarẹ ilẹ wa laye ijọba ologun, Ibrahim Babangida, ni ile re to wa ni Top Hill, niluu Minna.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kọkanla yii, ni ọkunrin naa balẹ sile Babangida, nibi ti wọn ti ṣe ipade idakọnkọ.

Bo tilẹ jẹ pe ipade kọrọ ni wọn ṣe, awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe gbogbo ohun ti wọn gbe yara sọ naa ko ni i se lori idibo ọdun to n bọ, nibi to ti ṣee ṣe ki Tinubu lọọ beere fun atilẹyin ọkunrin ti wọn maa n pe ni IBB yii.

Aṣiwaju ko da nikan lọ o, oun ati igbakeji rẹ ti won jọọ fẹẹ dupo, Kashim Shettima, Ọga agba ipolongo fun eto idibo aarẹ, to tun jẹ Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, Gomina ipinlẹ Kebbi, Atiku Bagudu, Abubakar Badaru ti ipinlẹ Jigawa atawọn mi-in bẹẹ.

 

Gomina ipinlẹ Kano, Ganduje,

Leave a Reply