Ọrẹoluwa Adedeji
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Aarẹ Bọla Tinubu ṣepade pọ pẹlu awọn olori eto aabo gbogbo nilẹ wa fungba akọkọ. Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni Olori awọn ọmọ ologun patapata nilẹ wa, Lucky Irabor, Olori awọn ṣọja, Lt. Gen. Farouk Yahaya, Olori ileesẹ awọn ọmọ oju omi Vice Marshal Awwal Gambo, Olori ileesẹ ofurufu, Air Marshal Isiaka Amao. Awọn yooku ni ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Usman Alkali Baba, Olori awọn ọtẹlẹmuyẹ to n ri sọrọ abẹle, Yusuf Bichi ati ọga agba fun ileeṣẹ to n ri sọrọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ okeere (Nigeria Intelligence Agency) Ahmed Rufai Abubakar.
Awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe lati fun okun eto aabo dan-in-dan-in latibẹre ijọba rẹ lo fa ipade awọn olori ẹsọ alaabo nilẹ wa naa.