Faith Adebọla
Bii awada kẹrikẹri ni kinni ọhun jọ, ṣugbọn ki i ṣe awada, nigba ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, fẹẹ ṣadura fẹgbẹ oṣelu rẹ, ṣugbọn to jẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, iyẹn Peoples Democratic Party, lo darukọ, to ṣadura fun.
Iṣẹlẹ yii waye nigba ti Tinubu pari ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ iṣide eto ipolongo ibo aarẹ rẹ ni papa iṣere Rwang Pam Stadium, to wa niluu Jos, ipinlẹ Plateau.
Bi Tinubu ti n kadii ọrọ rẹ lo bẹrẹ adura, o ni:
“K’Ọlọrun bu kun Naijiria, k’Ọlọrun bu kun PD…” lo ba danu duro lojiji nigba tawọn eeyan to rọgba yi i ka kọ haa. Ọrọ naa ya Amofin Ismail, to jẹ oluṣekokaari awọn ọdọ ninu igbimọ ipolongo aarẹ APC, niṣe lọkunrin naa sare fọwọ bo ẹnu ẹ nigba to gbọ ọrọ ti Tinubu sọ, gẹgẹ bo ṣe han ninu fidio kan ti wọn fi sori ẹrọ ayelujara.
Loju ẹsẹ ni Tinubu yi ọrọ rẹ pada, lo ba n tẹnu mọ “Ki Ọlọrun bu kun APC,” o si sọ ọ leralera bii ẹẹmẹta.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan to wo fidio yii n sọ nipa iṣẹlẹ ọhun, awọn kan ni aṣiwi ko to aṣisọ ni, wọn lo ṣihun ni, ko si sẹni tiyẹn o le ṣẹlẹ si, ṣugbọn ọpọ awọn mi-in lo ni ọjọ ogbo lo n da baba naa laamu, wọn ni ọpọ igba lẹnu ọjọ mẹta yii lo maa n ṣi ọrọ sọ, wọn ni agbara iranti rẹ ti walẹ, nitori ipo arugbo to wa, awọn kan tilẹ n sọ pe ko daa bawọn eeyan ṣe n da baba agbalagba yii laamu pe ko tẹsiwaju ninu idije funpo aarẹ, wọn ni niṣe lo yẹ ki wọn gba a lamọran lati lọọ sinmi jẹẹ, tori ba a ba dagba ju bantẹ oniru lọ, ọmọ ẹni la a bọ ọ fun.
Bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣe ami si adura Tinubu, wọn lo fontẹ lu iṣejọba awọn fun ọdun to n bọ niyẹn.