Jamiu Abayomi
Agbarijọpọ ẹgbẹ kan l’Oke-Ọya ti wọn pera wọn ni ‘The Northern Development Forum’ (NDF), ti kọ lẹta si Aarẹ Bọla Tinubu, wọn si ti fun un ni gbedeke ọsẹ meji pere lati tu gbogbo awọn Boko Haram to wa lẹwọn silẹ, ki o sanwo ‘gba ma binu’ fun wọn, ko si ṣeto ẹbun ẹkọ-ọfẹ fun wọn, bo ba n fẹ alaafia ni orile-ede Naijiria.
Ninu lẹta ti Agbẹnusọ ẹgbẹ NDF, Sheriff Abubakar, fi ranṣẹ lo ti kilọ fun Tinubu pe bi o ba fẹ ki awọn eeyan ara Oke-Ọya ati agbegbe rẹ wa ni alaafia, o gbọdọ tu awọn Boko Haram to pe ni ajafẹtọọ ọmọniyan yii silẹ gẹgẹ bi aarẹ to ti doloogbe, Umar Musa Yar’adua, ṣe ṣe lọdun 2009 fawọn ajafẹtọọ ọmọniyan ti Niger Delta.
Wọn tẹsiwaju pe lati ọdun mẹẹẹdogun ọhun ni ikọ Niger Delta ti n jẹgbadun ijọba awa-ara-wa ni Naijiria, ti wọn waa kọ awọn silẹ l’Oke-Ọya sinu oṣi ati iṣẹ.
Apa kan lẹta naa ka bayii pe, “Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, a n kọwe yii si yin gẹgẹ bii ọmọ Naijiria t’ọrọ n dun, to si n fẹ idajọ ododo ati iṣọkan lorilẹ-ede wa yii. Iṣẹlẹ to ṣẹ laipẹ yii ti tanmọlẹ si i pe ni kiakia ni awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan Oke-Ọya ti gbogbo eeyan mọ si Boko Haram, gbọdọ gba itusilẹ. Bi ẹ ko ba gbagbe pe ijọba Aarẹ Umar Yar’adua(Allah Yarhamuh) gbe iru igbesẹ yii kan naa fun awọn eeyan Niger Delta, nigba to wa nijọba.
“A n fi asiko yii rọ yin ki ẹ gba ibeere wa yii yẹwo, ki ẹ si gbe igbese lori rẹ kiakia lati le jẹ ki alaafia, ibaṣepọ ati iṣọkan jọba ni orile-ede Naijiria.
“A mọ pe ọpọ ninu awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan Niger Delta, ti wọn tu silẹ lọdun 2009, ni wọn ti di oloṣelu nla bayii, ti wọn si di ipo nla nla mu ni Naijiria lọwọlọwọ, bii olori ileegbimọ aṣofin, bakan naa lawọn kan ti di olokoowo nla, ti wọn si n daṣẹ silẹ lawujọ. A n fẹ iru nnkan bẹẹ fawọn Boko Haram.
“Eto itunisilẹ lahaamọ to waye fawọn Niger Delta, jẹ ki alaafia wa lagbegbe naa, ti ikọlu si dinku. Eto ẹkọ-ọfẹ, ironilagbara ati ipese iṣẹ fun wọn yii lo ṣokunfa rẹ.
“O ye wa pe ọpọ Boko Haram ni wọn ti tu silẹ latari eto De-radicalisation, Rehabilitation and Reintegration (DRR), tawọn ọmọ ologun ṣe, ṣugbọn ko ti i to, wọn gbọdọ ṣe si i.
” Bi ẹ ba tu awọn afẹmiṣofo Ariwa Naijiria silẹ, eyi yoo jẹ ki Naijiria tun wa ni iṣọkan ati itẹsiwaju, eyi yoo si fi aaye silẹ fun wa lati pe ipade alaafia, ti a o si sọrọ lori awọn ohun to n da omi alaafia Naijiria ru, ti ohun gbogbo yoo si niyanju.
“Aarẹ wa, ti ẹ ba le tu awọn ikọ yii silẹ, yoo jẹ ki awọn to ku ko awọn ohun ija ọwọ wọn silẹ, ti eyi yoo si jẹ ki agbega ati ilọsiwaju ba orile-ede wa.
” Lafikun, bi ẹ ba gbe igbesẹ yii, yoo fi ijọba yin han bii eyi to n ṣe deedee, paapaa lori ẹtọ ọmọnikeji, lai fi ti ẹya, ede, tabi ibugbe ṣe, yoo si tun fi han pe ẹ ko da ẹya kan yatọ sọtọ, eyi ni yoo jẹ ki ilọsiwaju wa, ki a si wa ni iṣọkan.
” A tun n rọ yin lẹẹkan si i, pe ki ẹ lo ọgbọn yii ati ifọmọniyan ṣe lati tu awọn Boko Haram yii silẹ lahaamọ. Idahun yin si ibeere wa yii yoo jẹ ki iyatọ ba gbogbo olugbe orilẹ-ede wa, ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo si le ṣapa wọn ninu rẹ. A si tun gbagbọ pe bi ẹ ba tẹle ilana ti wọn lo fun awọn Niger-Delta lọdun naa lọhun-un, eyi yoo jẹ ki iyatọ ba iwa ẹlẹyamẹya, ti gbogbo wa yoo si wa ni iṣọkan, ti alaafia yoo si jọba ni Naijiria.
“Ẹ ṣe pupọ fun asiko yin ti ẹ fi silẹ fun ọrọ pataki yii, a oo maa reti esi yin ati igbesẹ akin ti ẹ oo gbe lori ọrọ naa fun, ọjọ ọla to dara fun orile-ede wa”.
Bayii ni iwe ti ẹgbẹ itẹswaju Oke-Ọya (NDF), kọ si ofiisi Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe lọ.