Faith Adebọla
Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe ọkan oun balẹ pe nigba ti wọn yoo ba kede esi idibo sipo aarẹ to n lọ lọwọ yii, oun ni wọn maa kede gẹgẹ bii ẹni to yege ibo naa.
Tinubu sọrọ yii laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, nigba to n dibo n’Ikẹja, ipinlẹ Eko.
Nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ ni Tinubu de pẹlu ọkọ jiipu rẹ, bo ṣe bọọlẹ ni awọn agbofinro, awọn ẹṣọ, atawọn ọtẹlẹmuyẹ ti ṣugbaa rẹ, bẹẹ lawọn oniroyin ti wọn ti n duro de e da rẹi-rẹi tẹle e.
Ṣe ṣaaju ni ọmọ Tinubu, Fọlaṣade Ojo, to jẹ Iyalọja Jẹnẹra Eko ti kọkọ de sibudo idibo nọmba kẹrindinlaaadọta, eyi to wa l’Alausa, Ikẹja, o si fẹsẹ rin waa pade baba rẹ ni ibudo idibo nọmba kẹtalelogoji, nibi ti wọn ti maa n dibo tẹlẹ, amọ bi Tinubu ṣe de ni wọn sọ fun un pe wọn ti sun ibudo idibo rẹ siwaju, eyi to mu ko fẹsẹ rin lọ sibẹ, oun, iyawo rẹ, Olurẹmi, ati Fọlaṣade.
Obitibiti ero to n kokiki ọkunrin naa, ti wọn n pariwo Jagaban, iyẹn orukọ oye ti wọn tẹ mọ ọn lori, titi kan awọn oniroyin mu ki ayika naa ha gadigadi, bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ṣiṣẹ aṣelaagun lati dari awọn ero.
Nigbẹyin, tawọn mẹtẹẹta ti dibo, Tinubu ni inu oun dun pẹlu bi eto gbogbo ṣe lọ, o loun nireti pe didun lọsan yoo so foun, oun loun maa wọle.
O rọ awọn alatilẹyin rẹ lati fọkan balẹ.