Tinubu fẹẹ rin irinajo lọ siluu oyinbo

Faith Adebọla

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, yoo so ipolongo ati ipade ita gbangba ọlọkan-o-jọkan to n ṣe lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria rọ fun bii ọjọ meloo kan. Idi ni pe ọkunrin naa fẹẹ rin irinajo lọ si awọn ilu oyinbo kan laarin ọjọ kẹrin si ọjọ kejila, oṣu Kejila yii.

Gẹgẹ bii atẹjade kan ti ikọ to n polongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ APC gbe sori ẹrọ abẹyẹfo (twitter) wọn, wọn ni fun odidi ọjọ mẹjọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu ko fi ni i si nile, wọn ni yoo ṣabẹwo si awọn ilu kan, awọn aṣaaju awọn ilu nla atawọn alẹnulọrọ mi-in lati ṣepade pẹlu wọn lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria.

Lara awọn orileede ti Tinubu yoo lọ ni London, Amẹrika, France atawọn orileede kan to wa ninu ajọ orileede ilẹ Yuroopu, iyẹn European Union.

Wọn ni ti Tinubu ba de London, yoo ba awọn eeyan sọrọ ni gbagede ti wọn n pe ni Chatham House, bakan naa ni yoo ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in.

Wọn ni idi to fi so ipolongo ati ipade ita gbangba to n ṣe nilẹ wa rọ, to si fi fẹẹ lọọ ṣepade pẹlu awọn tiluu oyinbo ni lati fa oju awọn ara oke okun mọra fun ajọṣepọ pẹlu bi ẹgbẹ APC ti n mura lati yan ẹni ti yoo rọpo Buhari.

Ṣugbọn ọtọọtọ loju ti awọn eeyan fi n wo ọrọ naa. Bawọn kan ṣe sọ pe ko sohun to buru ninu irinajo ti oludije ẹgbẹ APC fẹẹ lọ  ni awọn mi-in n sọ pe niṣe ni baba fẹẹ lọọ ri awọn dokita rẹ niluu oyinbo, ṣugbọn ki ariwo ma baa pọ ju lo fi lọ ọ mọ awọn irinajo to n lọ wọnyi.

Eyi o wu ko jẹ, ohun ti awọn igbimọ rẹ sọ ni pe Tinubu fẹẹ lọọ ba awọn aṣaaju nla nla agbaye kan ṣepade lori ipinnu rẹ lati di aarẹ Naijiria ni, ọjọ mẹjọ pere ni yoo si lo.

 

Leave a Reply