Faith Adebọla, Eko
Ko si iyemeji kankan ninu ẹ mọ bayii pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, to tun jẹ Adari apapọ fun ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu, yoo dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lọdun to n bọ, baba naa ti gba fọọmu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti gba fọọmu lati dije fun ipo gomina ipinlẹ naa, fun saa keji.
Ba a ṣe gbọ, awọn alajọṣe ati alatilẹyin Tinubu ti wọn wa ninu ẹgbẹ Tinubu Support Groups (TSG), ni wọn ṣeto lati gba fọọmu ti APC n ta ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un miliọnu Naira (N100m) naa fun un, tori ọkunrin naa ṣi wa ni orileede Saudi Arabia, nibi to ti lọọ fun eto akanṣe adua to da lori idije fun ipo aarẹ ọhun.
Lara awọn to kọwọọrin lati gba fọọmu naa lolu ile ẹgbẹ APC to wa l’Opopona Blantyre, Wuse 2, Abuja, ni Aṣoju-ṣofin lati ẹkun idibo Ikẹja, James Faleke, Aṣoju-ṣofin lati Agege, Babatunde Adejare ati Akọwe fun ijọba apapọ tẹlẹ ri, Babachir Lawal.
Nnkan bii aago mẹta irọlẹ Furaidee ni wọn gba fọọmu naa lorukọ Tinubu.
Bakan naa ni ẹgbẹ TSG gba fọọmu ẹlẹgbẹrun lọna aadọta miliọnu Naira (N50m) fun gomina ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu.
Ṣaaju ni igbimọ awọn agbaagba ẹgbẹ APC l’Ekoo ti fẹnu ko pe awọn fara mọ ki Sanwo-Olu dije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ APC l’Ekoo, lẹẹkan si i.
Lara awọn to tun ti gba fọọmu lati dije dupo aarẹ ninu ẹgbe APC ni Gomina ipinlẹ Kogi, Yahya Bello, gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha.