Tinubu kọ lẹta sawọn aṣofin:Ẹ gba mi laaye lati ko ṣọja lọ si Niger

Adewale Adeoye

Olori orile-ede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti kọ lẹta sawọn aṣofin ilẹ wa, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, pe ki wọn gba oun laaye lati ko awọn ṣọja ilẹ wa lọọ koju awọn to ditẹ-gbajọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazoum, aarẹ orile-ede Niger, laipẹ yii.

Yatọ si pe Tinubu n beere pe ki wọn gba foun lati ko ṣọja ile wa lọ sorile-ede Niger, o tun ni ki wọn faṣẹ si i pe k’oun ja ina mọna-mọna ti orile-ede wa n fun awọn ara orile-ede yii, ki wọn si wa ninu okunkun biribiri titi tawọn to ditẹ-gbajọba lọwọ ijọba alagbada orile-ede naa maa fi tuuba.

Awọn igbesẹ ti Aarẹ Tinubu fẹẹ gbe yii wa ni ibamu pẹlu abajade ipade pataki kan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ‘Economic Community Of West African State’ (ECOWAS), eyi ti Tinubu jẹ aarẹ wọn.

Ninu lẹta ọhun ti Aarẹ kọ ranṣẹ sawọn ọmọ aṣofin lo ti sọ pe, ‘‘Awọn ọmọ ẹgbẹ ECOWAS ti mọ jẹ olori fun ti fẹnu ko nibi ipade ẹgbẹ wa to waye niluu Abuja, laipẹ yii pe ki i ṣohun to daa rara bawọn ṣọja ṣe ditẹ gbajọba lọwọ olori orile-ede Niger, Mohamed Bazoum. Taa si tun fẹnu ko pe ka sa gbogbo ipa wa lati da ijọba alagbada ti wọn n ṣe lorileese naa pada, ki alaafia le jọba. Abọ ipade wa ni pe ka ko awọn ṣọja lọọ koju awọn to ditẹ gbajọba naa, ka a si ri i pe wọn ṣe ohun ta a fẹ.  pata, ka a ri i daju pe a ti gbogbo ibode to woluu wa pa patapata lati fopin si bawọn ara orileede naa ati ọja wọn ṣe n wọ orile-ede wa. Jija ina mọna-mọna orile-ede Niger lulẹ, kawọn araalu naa si wa ninu okunkun biribiri. Ka si tun bẹ fun iranwọ awọn alaṣẹ ijọba ilẹ okeere gbogbo lati le jẹ kawọn ohun ta a fẹẹ ṣe yii kẹsẹjari layọ ati alaafia’’. Eyi atawọn ohun miiran ni Aarẹ Tinubu kọ sinu lẹta rẹ to fi ṣọwọ sawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja.

 

Leave a Reply