Tinubu nilo adura gbogbo ọmọ Naijiria tori ilera rẹ lasiko yii o – Atiku

Faith Adebọla

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti parọwa sawọn ọmọ Naijiria pe nibi tọrọ de yii, ko sohun meji ti ẹlẹgbẹ oun ti ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, tawọn jọọ dije funpo aarẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nilo latọdọ wọn ju ki wọn gbe ọwọ adura soke fun un gidigidi lọ, nitori ipo ti ilera rẹ wa lasiko yii.

Atiku sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, lori ikanni abẹyẹfo, tuita, ọkan lara awọn agbọrọsọ feto ipolongo ibo aarẹ rẹ, Amofin agba Daniel Bwala.

O kọ ọrọ naa bayii pe: “Ohun to ku-diẹ-ka-a-to gidi ni bawọn alatilẹyin Tinubu ṣe lọ n gbe awọn fọto ati fidio atijọ nipa Tinubu jade, ti wọn si n ju u sori ẹrọ ayelujara bii pe eyi ti wọn ṣẹṣẹ ya ni, eyi lo si jẹ kawọn eeyan mọ pe apamọ-pabo ati abosi kan n lọ lọwọ lori ọrọ ilera Tinubu ati ibi to wa ni pato bayii.

“Ohun ti Tinubu nilo latọdọ gbogbo awa ọmọ Naijiria rere ni adura, niṣe lo yẹ ka gbọwọ adua gidi soke fun un, dipo awọn nnkan radarada tawọn abẹṣinkawọ ti wọn yi Tinubu ka, ti wọn n sọrọ fawọn oniroyin, n ba kiri ni gbogbo igba yii.

“Awọn ẹgbẹ alatako ko sọrọ nipa ilera ati ibi ti Tinubu wa, ọrọ ẹjọ to wa ni kootu nipa eto idibo to waye kọja la gbaju mọ. Amọ niṣe lawọn alaimeyi-to-kan amugbalẹgbẹẹ oniroyin to yi i ka n gbe awọn fọto irọ ati fidio eke kan jade bii pe wọn ṣẹṣẹ ya a ni. Awọn alailọgbọn to n ṣe bii ọlọgbọn dede.”

Tẹ o ba gbagbe, o ti le lọsẹ mẹta bayii ti ọkunrin ti wọn fi joye Jagaban tilẹ Borgu yii, Tinubu, ti tẹkọ leti lọ siluu oyinbo. Awọn agbẹnusọ rẹ sọ pe niṣe ni baba ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin naa lọọ fara nisinmi, tori fun ọpọ oṣu lo ti fi kopa ninu eto ipolongo ibo ati idibo to waye kọja, eyi ti wọn kede nigbẹyin pe oun lo jawe olubori.

Wọn ni baba naa yoo de orileede France ati United Kingdom, ti yoo si kadii irinajo rẹ si Saudi Arabia, nibi ti yoo ti lọọ ṣe aaji, amọ ni bayii, ko sẹni to gburoo Tinubu o.

Leave a Reply