Faith Adebọla, Eko
Eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti sọ pe oun o fa ọmọ-oye kan kalẹ lati dije dupo ninu eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ niluu Eko, o si ṣekilọ pe kawọn ti wọn n fi orukọ oun purọ tete yaa jawọ ninu aṣa naa.
Nibi ipade pataki kan tawọn agbaagba ẹgbẹ oṣẹlu APC nilẹ Yoruba ṣe lọjọ Aiku, Sannde yii, nile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Marina, l’Erekuṣu Eko, ni Bọla Tinubu ti ṣekilọ ọhun.
Tinubu, to sọrọ lẹyin ti Oloye Bisi Akande ti pari ọrọ rẹ lori ipinnu tawọn agbaagba ọhun fẹnu ko le lori nipade wọn lori eto aabo to mẹhẹ nilẹ wa ni oun ni ọrọ pataki kan lati ba awọn oniroyin ati araalu sọ funra oun.
O ni oun ti gba ọpọ lẹta, bawọn kan ṣe n tẹ oun laago, bẹẹ lawọn eeyan n fi oriṣiiriṣii ọrọ ṣọwọ soun lori atẹ ayelujara, ti wọn n fẹsun kan oun pe oun sọ fawọn ondije kan pe ki wọn lọọ jokoo na, ki wọn fun awọn kan laaye, o lawọn kan si n sọ pe oun ti lawọn ọmọ-oye toun fẹẹ fa kalẹ lati dupo ninu eto ibo ijọba ibilẹ to sun mọle yii.
Baba naa ni irọ patapata lọrọ yii, oun o si nifẹẹ si bawọn eeyan ṣe n darukọ oun si ọpọ nnkan toun ko mọwọ-mẹsẹ nidii ẹ.
O loun ko ni ọmọ-oye kan, gbangba loun si n sọrọ yii, ẹnikẹni to ba fẹẹ jade dupo eyikeyii lanfaani lati ṣe bẹẹ, tonitọhun ba ti kunju oṣuwọn alakalẹ ti ajọ eleto idibo ati iwe ofin ẹgbẹ APC ṣe.
Tinubu ni loootọ loun fara mọ eto fifa ọmọ-oye kalẹ labẹle (consensus candidate) ati eto didibo yan ọmọ oye lawọn ibi kan, ṣugbọn eyi ko tumọ si pe oun lawọn ọmọ-oye toun buwọ le pe dandan ni ki wọn wọle.
“Ẹ lọọ kilọ fawọn ti wọn ba n gbero lati dana ijangbọn silẹ pe ko le saaye fun iru nnkan bẹẹ ninu eto idibo to n bọ yii o. Ati ọmọ-oye ti wọn fa kalẹ, ateyi ti wọn dibo yan, ipinnu tawọn adari ẹgbẹ ba ṣe lawọn ijọba ibilẹ kọọkan labẹ ge, emi o si si lara awọn to maa ṣeru ipinnu bẹẹ, ki lawọn eeyan waa n gbe orukọ mi pooyi ẹnu fun.
Gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC torukọ rẹ wa lakọọlẹ, to si lawọn ohun amuyẹ to ba ofin ajọ eleto idibo ati ti ẹgbẹ oṣelu wa (APC) mu lo lẹtọọ ati anfaani lati jade dupo, ko si sẹni to gbọdọ tẹ iru ẹtọ bẹẹ loju nibikibi.”
Gbagbaagba ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Abẹnugan awọn aṣoju-ṣofin apapọ, Fẹmi Gbajabiamila duro sẹgbẹẹ Tinubu bo ṣe n sọ ero ati ikilọ naa jade l’Ekoo.