Monisọla Saka
Pẹlu bi Donald Trump, ṣe wọlẹ ibo gẹgẹ bii Aarẹ ilẹ Amẹrika lẹẹkeji, Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ranṣẹ ikini ku oriire si i.
Trump to jẹ Aarẹ kẹtadinlaaadọta nilẹ Amẹrika, ni Tinubu ni inu oun dun, bẹẹ loun ṣetan lati ri i daju pe ajọṣepọ laarin orilẹ-ede mejeeji duroo re si i, ti anfaani rẹpẹtẹ yoo si tibẹ jade.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe oludamọran pataki si Aarẹ Tinubu kede iṣẹ oriire naa.
Ninu atẹjade ti o pe akọle rẹ ni ‘Aarẹ Tinubu ki Aarẹ Trump ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ku oriire’ lo ti ni, “Lapapọ, a le jọ fọwọsowọpọ lori eto ọrọ aje, ki a mu igbelarugẹ ba eto aabo ati alaafia, ati adojukọ agbaye to n pa awọn ọmọ orilẹ-ede wa lara”.
O ni oriire ijawe olubori Trump yii ṣafihan igbẹkẹle ati igboya tawọn eeyan ilẹ Amẹrika ni ninu iṣejọba rẹ.
Bẹẹ lo tun ki awọn ajọ eleto idibo Amẹrika ku oriire lori erongba wọn lati mu ẹsẹ ijọba awa-ara-wa duro.
“Aarẹ Tinubu gbagbọ pe, nipa wiwo iriri Aarẹ Trump gẹgẹ bii aarẹ karundinlaaadọta nilẹ Amẹrika, lasiko iṣejọba rẹ akọkọ laarin ọdun 2017 si 2021, to si tun fẹẹ pada si White House, ti i ṣe ile ijọba wọn yii gẹgẹ bii aarẹ ẹlẹẹkẹtadinlaaadọta wọn, yoo mu asiko ti yoo ṣanfaani fun eto ọrọ aje ati idagbasoke ajọṣepọ laarin ilẹ Afrika ati ilẹ Amẹrika gbooro si i ni”.
Bakan naa ni Tinubu ni oun mọ ipa agbara, ipo ati aṣẹ ti ilẹ Amẹrika ni lati dari gbogbo nnakan to n lọ lagbaaye, ati pe oun mọ daju pe labẹ akoso Aarẹ Trump, yoo mu gbogbo agbanla aye debi alaafia ati oriire.
Trump, to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78), lasiko to di Aarẹ ilẹ Amẹrika fun igba keji yii, ni Aarẹ ilẹ Amẹrika to lọjọ lori ju lọ.
Laarin awọn to dije dupo to ṣẹṣẹ wa sopin yii, Donald Trump ati Arabinrin Kamala Harris, ni wọn le waju. Ida mọkandinlaaadọta (51%), ni Trump ni, nigba ti Harris, to wa nipo keji, ni ibo ida mẹtadinlaaadọta ati aabọ (47.5%)