Faith Adebọla
Aarẹ orileede yii, Bọla Ahmed Tinubu ti paṣẹ ki Ọga agba banki apapọ ilẹ wa, iyẹn Central Bank of Nigeria, CBN, Ọgbẹni Godwin Emefiele, ṣi lọọ rọọkun nile na, wọn ti jawee ‘gbele ẹ’ fọkunrin naa lẹyẹ-o-sọka.
Atẹjade kan lati ọwọ Oludari eto iroyin fun ọfiisi Akọwe ijọba apapọ, Ọgbẹni Willie Bassey, eyi ti wọn fi lede lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ti fidi ọrọ yii mulẹ.
Atẹjade naa sọ pe igbesẹ yii pọn dandan lati le raaye ṣe awọn iwadii to lọọrin lori ipa ti Emefiele ko lori atunto owo Naira ilẹ wa ti banki apapọ naa gun le lẹnu lọọlọọ yii.
Aarẹ ti paṣẹ pe ki Emefiele ko gbogbo awọn ẹru ijọba to wa nikaawọ silẹ lẹsẹkẹsẹ, ko si faṣẹ le Igbakeji rẹ, lẹka akoso banki naa, lọwọ. Wọn loun ni ko maa ṣi maa ṣakoso banki apapọ ọhun lọ naa fun saa yii.
Tẹ o ba gbagbe, awuyewuye ti ko mọ niwọn lo waye lori atunto owo naira, ipaarọ awọn owo beba naira atijọ si tuntun, eyi to fa yanpọnyanrin ṣaaju eto idibo gbogbogboo ti ọdun yii, ati lẹyin rẹ.
CAPTION