Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti paṣẹ fun Minisita eto idajọ lorileede yii, Ọgbẹni Lateef Fagbemi (SAN) laṣẹ pe ko tete yẹ iwe ipẹjọ lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan awọn ọmọ keekeeke ti wọn ko wa sile-ẹjọ giga kan l’Abuja, laipẹ yii wo, ko si gbe igbesẹ gidi nipa rẹ.
Latigba ti ẹjọ awọn ọmọ keekeeke naa ti waye nile-ẹjọ giga kan lọsẹ to kọja yii, lawọn ọmọ orileede yii nile ati lẹyin odi ti n bẹnu atẹ lu ijọba Naijiria pe ohun ti wọn ṣe fawọn ọmọde naa ko daa rara. Nibi tọrọ ọhun le de, ki i ṣe awọn ọmọ yii nikan ni wọn n sọrọ ṣakaṣaka s’ijọba, awọn agbaye paapaa ko fojuure wo iṣẹlẹ ọhun rara.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Aarẹ Tinubu paṣẹ fun minisita eto idajọ pe ko tete ṣe agbeyẹwo iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọ keekeeke naa, ko si gbe igbesẹ gidi lori ọrọ ọhun.
ALAROYE ti gbe iroyin ọhun jade tẹlẹ pe iwaju Onidaajọ Obiora Egwuata, tile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, ni wọn foju awọn ọmọ keekeeke naa ba lọsẹ to kọja yii.
Marun-un ninu wọn lo ṣubu lulẹ gbalaja lasiko ti wọn ko wọn de kootu lọjọ naa nitori airi itọju to peye lọgba ẹwọn ti wọn wa.
Iṣẹlẹ ọhun lo fa ki awọn wọda atawọn ọlọpaa to ko awọn ọmọde naa wa fi n sa sọtun-un, sa sosi ninu kootu lati doola ẹmi wọn.
Lẹyin ti wọn gbadun diẹ tan ni wọn ba tun da gbogbo wọn pada sinu ọgba ẹwọn Kuje, niluu Abuja, ti adajọ ọhun si ni ki wọn gba beeli wọn pẹlu miliọnu mẹwaa Naira lẹnikọọkan wọn.
Ṣa o, ọkan lara agbẹjọro awọn ọmọ keekeeke naa, Deji Adeyanju, ti bẹnu atẹ lu owo tabua ti adajọ ni ki wọn fi gba beeli awọn ọmọ naa, nitori ti wọn ti wa lọgba ẹwọn lati inu oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Lori ọrọ awọn ọmọ keekeeke naa, oniruuru awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan lorileede yii ati l’Oke-Okun ni wọn ti bẹnu atẹ lu iṣakooso ijọba Aarẹ Tinubu pe ọwọ lile lo fi mu ọrọ awọn araalu lasiko iṣejọba rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, asiko iwọde lati fopin si ijọba ti ko dara tawọn ọdọ gun le lorileede yii, eyi ti wọn bẹrẹ ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn tori ẹ mu awọn ọmọ naa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ba dukia ijọba jẹ lasiko iwọde ọhun, bẹẹ ni wọn tun fẹsun iditẹ gbajọba kan wọn pẹlu bi wọn ṣe ni wọn gbe asia ilẹ Russia dani lasiko iwọde yii. Itumọ eyi ni pe wọn n pe orileede naa lati waa da si wahala to wa nilẹ wa. Bẹẹ ni wọn ni wọn tun n pariwo pe ki ṣoja waa gbajọba.
Latigba naa lawọn ọmọ keekeeke ọhun ti wa lọgba ẹwọn, ko too di pe igbẹjọ bẹrẹ lori ẹjọ tijọba n ba wọn ṣe.