Tinubu yoo ṣatunṣe sileeṣẹ eto ilera to ba di aarẹ- APC

Monisọla Saka

Ẹka ti wọn ti n ri si ọrọ eto ilera ninu ikọ ipolongo eleto idibo fẹgbẹ oṣelu APC (PCC), ti fawọn eeyan lọkan balẹ pe ti ọga awọn ba fi le wọle sipo aarẹ, yoo ṣe atunṣe rere sileeṣẹ eto ilera ilẹ Naijiria.

Adari ẹka eto ilera ikọ PCC, Dokita Ikechukwu Odikpo, lo sọ eleyii di mimọ fawọn oniroyin niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

Odikpo ṣalaye pe gbogbo awọn kudiẹ-kudiẹ ati alafo to yọ silẹ lẹka eto ilera ni Tinubu yoo mu ayipada rere ba. O tẹsiwaju pe erongba Tinubu lati ṣatunṣe seto ilera, ko si tun pese ayika to rọrun fawọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo,o ni eyi yoo fopin si ọrọ awọn dokita ti wọn n forilẹ-ede yii silẹ lọ silẹ ibomi-in.

O ni, “Ti igbayegbadun awọn dokita ba jẹ wọn logun, ti wọn si tun pese ayika to daa fun wọn lati ṣiṣẹ wọn, leyii ti i ṣe ọkan ninu awọn eto ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti la kalẹ, pẹlu iwuri lawọn oṣiṣẹ eleto ilera yoo fi maa ṣiṣẹ wọn, yoo si tun din wahala wọn ku.

Ẹlẹẹkeji ni pe gẹgẹ bi Tinubu ṣe ṣe nipinlẹ Eko, yoo ri i daju pe eto ilera to poju owo wa fawọn eeyan ilẹ yii, ọrọ pe awọn dokita wa n lọ si oke okun yoo dinku, gbogbo ọna ti Tinubu gba lati sọ ipinlẹ Eko di nla ni yoo gba lati ṣejọba ilẹ Naijiria to ba depo”.

Odikpo to ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bii aṣaaju to ni afojusun, sọ pe Tinubu yoo jokoo ipade pẹlu awọn tọrọ kan lẹka eto ilera lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii.

O ni ipade ita gbangba tawọn ti ṣeto ẹ silẹ yii ni Tinubu fẹẹ lo anfaani ẹ, lati ba awọn dokita atawọn oṣiṣẹ eleto ilera sọrọ, lori awọn ọna ti wọn le gba fi ṣe atunto ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede yii.

Dokita Joseph Kigbu, ti i ṣe Akọwe igbimọ PCC, sọ fun ileeṣẹ iroyin ilẹ wa, NAN, lori awọn ilakaka Tinubu lati ṣe agbende eto ilera to yaayi atawọn aṣeyọri tawọn ijọba APC to wa nipo ti ṣe nileeṣẹ naa.

Kigbu ni Tinubu ti ṣeleri lati mu imugbooro ba eto ilera awọn araalu, yoo si kọ awọn ile iwosan alabọọde kọọkan sibudo eto idibo kọọkan jake-jado orilẹ-ede yii.

O ni erongba Tinubu ni lati lo iru aṣeyọri ẹ nipinlẹ Eko, eyi to sọ ọ di ipinlẹ kan ṣoṣo nilẹ Naijiria ti akọsilẹ iku awọn alaboyun ko ti wọpọ, lati dari awọn eeyan, ki iku alaboyun lori ikunlẹ atawọn ajakalẹ arun to n fẹmi awọn eeyan ṣofo le dinku jọjọ.

Akọwe to bara jẹ lori akaimọye iku awọn alaboyun lorilẹ-ede Naijiria yii, sọ pe Tinubu yoo gbe eto kan kalẹ ti yoo nipa lati daabo bo ẹmi iya ati ọmọ tuntun lasiko ti alaboyun ba n rọbi lọwọ. O waa rọ awọn eeyan lati dibo wọn fun Tinubu, ki gbogbo ala aṣeyọri rẹ forilẹ-ede Naijiria le wa si imuṣẹ.

Leave a Reply