Tirela meji fori sọraa wọn, eeyan mẹfa lo ku n’Imẹsi-Ile

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Eeyan mẹfa lo pade iku ojiji lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an yii, lasiko ti mọto tirela fori sọ ara wọn ni ori-oke Imẹsi ile, nipinlẹ Ọṣun.

Eeyan mẹtadinlogun ni wọn wa ninu tirela mejeeji, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣe wi, eeyan mọkanla lo si fara pa ninu ijamba naa.

Ọkan lara awọn tirela naa jẹ DAF, alawọ pupa, nigba ti ekeji jẹ Mack, alawọ buluu, ṣugbọn ko si eyi to ni nọmba ninu awọn mejeeji.

Ogungbemi ṣalaye pe awọn ti wọn wa lagbegbe naa ti gbe okuu marun-un lara awọn to doloogbe ọhun lọ sileewosan UNIOSUN, niluu Oṣogbo, ko too di pe awọn ajọ ẹṣọ ojuupopo debẹ.

O ni ẹni kẹfa ha sabẹ tirela, maṣinni nla lawọn fi yọ ọ jade. O sọ siwaju pe gbogbo ẹru awọn ti wọn wa ninu tirela naa lo ti wa ni agọ ọlọpaa ilu Imẹsi-Ile.

Ọga agba ajọ naa l’Ọṣun, Henry Benemaisia, waa ke si awọn awakọ lati maa fẹṣọ ṣe ti wọn ba n gun ori-oke, paapaa, lasiko ojo yii.

 

Leave a Reply